O. Daf 150:1-5
O. Daf 150:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ fi iyìn fun Oluwa. Ẹ fi iyìn fun Ọlọrun ninu ibi mimọ́ rẹ̀; yìn i ninu ofurufu oju-ọrun agbara rẹ̀. Yìn i nitori iṣẹ agbara rẹ̀: yìn i gẹgẹ bi titobi nla rẹ̀. Fi ohùn ipè yìn i: fi ohun-èlo orin ati duru yìn i. Fi ìlu ati ijó yìn i: fi ohun ọnà orin olokùn ati fère yìn i. Ẹ yìn i lara aro olohùn òke: ẹ yìn i lara aro olohùn goro
O. Daf 150:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ yin OLUWA! Ẹ yin Ọlọrun ninu ibi mímọ́ rẹ̀; ẹ yìn ín ninu òfuurufú rẹ̀ tí ó lágbára. Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ ńlá rẹ̀; ẹ yìn ín nítorí pé ó tóbi pupọ. Ẹ fi ariwo fèrè yìn ín; ẹ fi fèrè ati hapu yìn ín. Ẹ fi ìlù ati ijó yìn ín; ẹ fi gòjé ati dùùrù yìn ín. Ẹ fi aro olóhùn òkè yìn ín; ẹ fi aro olóhùn gooro yìn ín.
O. Daf 150:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ fi ìyìn fún OLúWA. Ẹ fi ìyìn fún Ọlọ́run ní ibi mímọ́ rẹ̀ Ẹ yìn ín nínú agbára ọ̀run rẹ̀. Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ agbára rẹ̀. Ẹ yìn ín fún títóbi rẹ̀ tí ó tayọ̀. Ẹ fi ohùn ìpè yìn ín. Ẹ fi ohun èlò orin yìn ín. Ẹ fi ohun èlò orin àti ijó yìn ín fi ohun èlò orin olókùn àti ìpè yìn ín Ẹ yìn ín pẹ̀lú aro olóhùn òkè, Ẹ yìn ín lára aro olóhùn gooro.