ORIN DAFIDI 150

150
Ẹ yin OLUWA
1Ẹ yin OLUWA!
Ẹ yin Ọlọrun ninu ibi mímọ́ rẹ̀;
ẹ yìn ín ninu òfuurufú rẹ̀ tí ó lágbára.
2Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ ńlá rẹ̀;
ẹ yìn ín nítorí pé ó tóbi pupọ.
3Ẹ fi ariwo fèrè yìn ín;
ẹ fi fèrè ati hapu yìn ín.
4Ẹ fi ìlù ati ijó yìn ín;
ẹ fi gòjé ati dùùrù yìn ín.
5Ẹ fi aro olóhùn òkè yìn ín;
ẹ fi aro olóhùn gooro yìn ín.
6Kí gbogbo nǹkan ẹlẹ́mìí yin OLUWA!
Ẹ yin OLUWA!

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 150: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀