O. Daf 146:1-10
O. Daf 146:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ fi iyìn fun Oluwa. Fi iyìn fun Oluwa, iwọ ọkàn mi. Nigbati mo wà lãye li emi o ma fi iyìn fun Oluwa: emi o ma kọrin iyìn si Ọlọrun mi, nigbati mo wà. Ẹ máṣe gbẹkẹ nyin le awọn ọmọ-alade, ani le ọmọ-enia, lọwọ ẹniti kò si iranlọwọ. Ẹmi rẹ̀ jade lọ, o pada si erupẹ rẹ̀; li ọjọ na gan, ìro inu rẹ̀ run. Ibukún ni fun ẹniti o ni Ọlọrun Jakobu fun iranlọwọ rẹ̀, ireti ẹniti mbẹ lọdọ Oluwa Ọlọrun rẹ̀: Ẹniti o da ọrun on aiye, okun ati ohun ti o wà ninu wọn: ẹniti o pa otitọ mọ́ titi aiye: Ẹniti o nṣe idajọ fun ẹni-inilara: ẹniti o nfi onjẹ fun ẹniti ebi npa. Oluwa tú awọn aratubu silẹ: Oluwa ṣi oju awọn afọju: Oluwa gbé awọn ti a tẹ̀ lori ba dide; Oluwa fẹ awọn olododo: Oluwa pa awọn alejo mọ́; o tù awọn alainibaba ati opo lara: ṣugbọn ọ̀na awọn enia buburu ni yio darú. Oluwa yio jọba lailai, ani Ọlọrun rẹ, iwọ Sioni, lati iran-diran gbogbo. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.
O. Daf 146:1-10 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ yin OLUWA! Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi. N óo máa yin OLUWA níwọ̀n ìgbà tí mo wà láyé; n óo máa kọrin ìyìn sí Ọlọrun mi níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè. Má gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìjòyè; eniyan ni wọ́n, kò sì sí ìgbàlà lọ́dọ̀ wọn. Bí ẹ̀mí wọn bá ti bọ́, wọn á pada di erùpẹ̀, ní ọjọ́ náà sì ni èrò inú wọn óo di ègbé. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó fi Ọlọrun Jakọbu ṣe olùrànlọ́wọ́ rẹ̀, tí ó gbójú lé OLUWA, Ọlọrun rẹ̀. Ọlọrun tí ó dá ọ̀run ati ayé, òkun ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀; Ọlọrun tíí máa ń pa àdéhùn rẹ̀ mọ́ títí lae, ẹni tíí máa ń dá ẹjọ́ òdodo fún àwọn tí a ni lára; tí ń fún àwọn tí ebi ń pa ní oúnjẹ, OLUWA tíí tú àwọn tí ó wà ninu ìdè sílẹ̀. A máa la ojú àwọn afọ́jú, a máa gbé àwọn tí a tẹrí wọn ba dúró; ó fẹ́ràn àwọn olódodo. OLUWA ni olùṣọ́ àwọn àlejò, òun ni alátìlẹ́yìn àwọn opó ati aláìníbaba, ṣugbọn a máa da ète àwọn eniyan burúkú rú. OLUWA yóo jọba títí lae, Sioni, Ọlọrun rẹ yóo jọba láti ìran dé ìran.
O. Daf 146:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ fi ìyìn fún OLúWA. Fi ìyìn fún OLúWA, ìwọ ọkàn mi. Èmi yóò yin OLúWA ní gbogbo ayé mi; Èmi yóò kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láààyè. Ẹ má ṣe ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ọmọ-aládé, àní, ọmọ ènìyàn, lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́. Ẹ̀mí rẹ jáde lọ, ó padà sí erùpẹ̀: Ní ọjọ́ náà gan, èrò wọn yóò di òfo: Ìbùkún ni fún ẹni tí Ọlọ́run Jakọbu ń ṣe ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ tí ìrètí rẹ̀ wà nínú OLúWA Ọlọ́run rẹ̀. Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ayé, òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn, ẹni tí ó pa òtítọ́ mọ́ títí ayé. Ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí a ni lára tí ó fi oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa OLúWA, tú àwọn oǹdè sílẹ̀ (ẹlẹ́wọ̀n) OLúWA mú àwọn afọ́jú ríran, OLúWA, gbé àwọn tí a rẹ̀ sílẹ̀ ga, OLúWA fẹ́ràn àwọn olódodo. OLúWA ń dá ààbò bo àwọn àlejò ó sì ń dá àwọn aláìní baba àti opó sí ṣùgbọ́n ó ba ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú jẹ́. OLúWA jẹ ọba títí láé; Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni, àti fún gbogbo ìran.