ORIN DAFIDI 146

146
Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA
1Ẹ yin OLUWA!
Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi.
2N óo máa yin OLUWA níwọ̀n ìgbà tí mo wà láyé;
n óo máa kọrin ìyìn sí Ọlọrun mi níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè.
3Má gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìjòyè;
eniyan ni wọ́n, kò sì sí ìgbàlà lọ́dọ̀ wọn.
4Bí ẹ̀mí wọn bá ti bọ́, wọn á pada di erùpẹ̀,
ní ọjọ́ náà sì ni èrò inú wọn óo di ègbé.
5Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó fi Ọlọrun Jakọbu ṣe olùrànlọ́wọ́ rẹ̀,
tí ó gbójú lé OLUWA, Ọlọrun rẹ̀.
6Ọlọrun tí ó dá ọ̀run ati ayé,
òkun ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀;
Ọlọrun tíí máa ń pa àdéhùn rẹ̀ mọ́ títí lae,#A. Apo 4:24; 14:15
7ẹni tíí máa ń dá ẹjọ́ òdodo fún àwọn tí a ni lára;
tí ń fún àwọn tí ebi ń pa ní oúnjẹ,
OLUWA tíí tú àwọn tí ó wà ninu ìdè sílẹ̀.
8A máa la ojú àwọn afọ́jú,
a máa gbé àwọn tí a tẹrí wọn ba dúró;
ó fẹ́ràn àwọn olódodo.
9OLUWA ni olùṣọ́ àwọn àlejò,
òun ni alátìlẹ́yìn àwọn opó ati aláìníbaba,
ṣugbọn a máa da ète àwọn eniyan burúkú rú.
10OLUWA yóo jọba títí lae,
Sioni, Ọlọrun rẹ yóo jọba láti ìran dé ìran.
Ẹ yin OLUWA.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 146: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa