ORIN DAFIDI 145

145
Orin Ìyìn
1Èmi óo gbé ọ ga, Ọlọrun mi, Ọba mi,
n óo máa yin orúkọ rẹ lae ati laelae.
2Lojoojumọ ni n óo máa yìn ọ́,
tí n óo máa yin orúkọ rẹ lae ati laelae.
3OLUWA tóbi, ìyìn sì yẹ ẹ́ lọpọlọpọ;
àwámárìídìí ni títóbi rẹ̀.
4Láti ìran dé ìran ni a óo máa yin iṣẹ́ rẹ,
tí a óo sì máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ agbára ńlá rẹ.
5Èmi óo máa ṣe àṣàrò lórí ẹwà ògo ọlá ńlá rẹ,
ati iṣẹ́ ìyanu rẹ.
6Eniyan óo máa kéde iṣẹ́ agbára rẹ tí ó yani lẹ́nu,
èmi óo sì máa polongo títóbi rẹ.
7Wọn óo máa pòkìkí bí oore rẹ ti pọ̀ tó,
wọn óo sì máa kọrin sókè nípa òdodo rẹ.
8Aláàánú ni OLUWA, olóore sì ni;
kì í yára bínú, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀.
9OLUWA ṣeun fún gbogbo eniyan,
àánú rẹ̀ sì ń bẹ lórí gbogbo ohun tí ó dá.
10OLUWA, gbogbo ohun tí o dá ni yóo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ,
àwọn eniyan mímọ́ rẹ yóo sì máa yìn ọ́.
11Wọn óo máa ròyìn ògo ìjọba rẹ,
wọn óo sì máa sọ nípa agbára rẹ,
12láti mú àwọn eniyan mọ agbára rẹ,
ati ẹwà ògo ìjọba rẹ.
13Ìjọba ayérayé ni ìjọba rẹ,
yóo sì máa wà láti ìran dé ìran.
Olóòótọ́ ni OLUWA ninu gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀,
olóore ọ̀fẹ́ sì ni ninu gbogbo ìṣe rẹ̀.
14OLUWA gbé gbogbo àwọn tí ń ṣubú lọ dìde,
ó sì gbé gbogbo àwọn tí a tẹrí wọn ba nàró.
15Ojú gbogbo eniyan ń wò ọ́,
o sì fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àsìkò.
16Ìwọ la ọwọ́ rẹ,
o sì tẹ́ gbogbo ẹ̀dá alààyè lọ́rùn.
17Olódodo ni OLUWA ninu gbogbo ọ̀nà rẹ̀,
aláàánú sì ni ninu gbogbo ìṣe rẹ̀.
18OLUWA súnmọ́ gbogbo àwọn tí ń pè é,
àní, àwọn tí ń pè é tọkàntọkàn.
19Ó ń tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ lọ́rùn;
ó ń gbọ́ igbe wọn, ó sì ń gbà wọ́n.
20OLUWA dá gbogbo àwọn tí ó fẹ́ ẹ sí,
ṣugbọn yóo pa gbogbo àwọn eniyan burúkú run.
21Ẹnu mi yóo máa sọ̀rọ̀ ìyìn OLUWA;
kí gbogbo ẹ̀dá máa yin orúkọ rẹ̀ lae ati laelae.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 145: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa