ORIN DAFIDI 144
144
Ọpẹ́ fún Ìṣẹ́gun
1Ìyìn ni fún OLUWA, àpáta mi,
ẹni tí ó kọ́ mi ní ìjà jíjà,
tí ó kọ́ mi ní iṣẹ́ ogun.
2Òun ni àpáta mi, ààbò mi, odi mi, olùdáǹdè mi,
asà mi, ẹni tí mo sá di.
Òun ni ó tẹrí àwọn eniyan ba lábẹ́ rẹ̀.
3OLUWA, kí ni eniyan jẹ́, tí o fi ń náání rẹ̀?
Kí sì ni ọmọ eniyan tí o fi ń ranti rẹ̀?
4Eniyan dàbí èémí,
ọjọ́ ayé rẹ̀ sì dàbí òjìji tí ń kọjá lọ.#Job 7:17-18; O. Daf 8:4
5OLUWA, fa ojú ọ̀run wá sílẹ̀, kí o sì sọ̀kalẹ̀ wá,
fọwọ́ kan àwọn òkè ńlá, kí wọ́n máa rú èéfín.
6Jẹ́ kí mànàmáná kọ, kí o sì tú wọn ká,
ta ọfà rẹ, kí o tú wọn ká.
7Na ọwọ́ rẹ sílẹ̀ láti òkè,
kí o yọ mí ninu ibú omi;
kí o sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn àjèjì,
8tí ẹnu wọn kún fún irọ́,
tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì kún fún èké.
9Ọlọrun, n óo kọ orin titun sí ọ,
n óo fi hapu olókùn mẹ́wàá kọrin sí ọ.
10Ìwọ ni ò ń fún àwọn ọba ní ìṣẹ́gun,
tí o sì gba Dafidi, iranṣẹ rẹ, là.
11Gbà mí lọ́wọ́ idà ìkà,
gbà mí lọ́wọ́ àwọn àjèjì,
tí ẹnu wọ́n kún fún irọ́,
tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì kún fún èké.
12Ní ìgbà èwe àwọn ọdọmọkunrin wa,
jẹ́ kí wọ́n dàbí igi tí a gbìn tí ó dàgbà,
kí àwọn ọdọmọbinrin wa dàbí òpó igun ilé,
tí a ṣiṣẹ́ ọnà sí bíi ti ààfin ọba.
13Kí àká wa kún fún oniruuru oúnjẹ,
kí àwọn aguntan wa bí ẹgbẹẹgbẹrun,
àní, ẹgbẹẹgbaarun ninu pápá oko wa.
14Kí àwọn mààlúù wa lóyún,
kí wọ́n má rọ́nú, kí wọ́n má bí òkúmọ;
kí ó má sí ariwo àjálù ní ìgboro wa.
15Ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí ó ní irú ibukun yìí;
ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí OLUWA jẹ́ Ọlọrun wọn.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 144: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010