O. Daf 146
146
Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA
1Ẹ fi iyìn fun Oluwa. Fi iyìn fun Oluwa, iwọ ọkàn mi.
2Nigbati mo wà lãye li emi o ma fi iyìn fun Oluwa: emi o ma kọrin iyìn si Ọlọrun mi, nigbati mo wà.
3Ẹ máṣe gbẹkẹ nyin le awọn ọmọ-alade, ani le ọmọ-enia, lọwọ ẹniti kò si iranlọwọ.
4Ẹmi rẹ̀ jade lọ, o pada si erupẹ rẹ̀; li ọjọ na gan, ìro inu rẹ̀ run.
5Ibukún ni fun ẹniti o ni Ọlọrun Jakobu fun iranlọwọ rẹ̀, ireti ẹniti mbẹ lọdọ Oluwa Ọlọrun rẹ̀:
6Ẹniti o da ọrun on aiye, okun ati ohun ti o wà ninu wọn: ẹniti o pa otitọ mọ́ titi aiye:
7Ẹniti o nṣe idajọ fun ẹni-inilara: ẹniti o nfi onjẹ fun ẹniti ebi npa. Oluwa tú awọn aratubu silẹ:
8Oluwa ṣi oju awọn afọju: Oluwa gbé awọn ti a tẹ̀ lori ba dide; Oluwa fẹ awọn olododo:
9Oluwa pa awọn alejo mọ́; o tù awọn alainibaba ati opo lara: ṣugbọn ọ̀na awọn enia buburu ni yio darú.
10Oluwa yio jọba lailai, ani Ọlọrun rẹ, iwọ Sioni, lati iran-diran gbogbo. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
O. Daf 146: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.