O. Daf 144:2-8
O. Daf 144:2-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Õre mi, ati odi-agbara mi; ile-iṣọ giga, ati olugbala mi; asà mi, ati ẹniti mo gbẹkẹle; eniti o tẹri awọn enia mi ba labẹ mi. Oluwa, kili enia, ti iwọ fi nkiye si i! tabi ọmọ enia, ti iwọ fi nronú rẹ̀! Enia dabi asan: bi ojìji ti nkọja lọ li ọjọ rẹ̀. Oluwa, tẹ̀ ọrun rẹ ba, ki o si sọ̀kalẹ: tọ́ awọn òke nla, nwọn o si ru ẽfin. Kọ manamana jade, ki o si tú wọn ka: ta ọfà rẹ ki o si dà wọn rú. Rán ọwọ rẹ lati òke wá; yọ mi, ki o si gbà mi kuro ninu omi nla, li ọwọ awọn ọmọ àjeji. Ẹnu ẹniti nsọ̀rọ asan, ọwọ ọtún wọn si jẹ ọwọ ọtún eke.
O. Daf 144:2-8 Yoruba Bible (YCE)
Òun ni àpáta mi, ààbò mi, odi mi, olùdáǹdè mi, asà mi, ẹni tí mo sá di. Òun ni ó tẹrí àwọn eniyan ba lábẹ́ rẹ̀. OLUWA, kí ni eniyan jẹ́, tí o fi ń náání rẹ̀? Kí sì ni ọmọ eniyan tí o fi ń ranti rẹ̀? Eniyan dàbí èémí, ọjọ́ ayé rẹ̀ sì dàbí òjìji tí ń kọjá lọ. OLUWA, fa ojú ọ̀run wá sílẹ̀, kí o sì sọ̀kalẹ̀ wá, fọwọ́ kan àwọn òkè ńlá, kí wọ́n máa rú èéfín. Jẹ́ kí mànàmáná kọ, kí o sì tú wọn ká, ta ọfà rẹ, kí o tú wọn ká. Na ọwọ́ rẹ sílẹ̀ láti òkè, kí o yọ mí ninu ibú omi; kí o sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn àjèjì, tí ẹnu wọn kún fún irọ́, tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì kún fún èké.
O. Daf 144:2-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Òun ni Ọlọ́run ìfẹ́ mi àti odi alágbára mi, ibi gíga mi àti olùgbàlà mi, asà mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé, ẹni tí ó tẹrí àwọn ènìyàn ba lábẹ́ mi. OLúWA, kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣàníyàn fún un, tàbí ọmọ ènìyàn tí ìwọ fi ń ronú nípa rẹ̀? Ènìyàn rí bí èmi; ọjọ́ rẹ̀ rí bí òjìji tí ń kọjá lọ. Tẹ ọ̀run rẹ ba, OLúWA, kí o sì sọ̀kalẹ̀; tọ́ àwọn òkè ńlá wọn yóò sí rú èéfín. Rán mọ̀nàmọ́ná kí ó sì fọ́n àwọn ọ̀tá ká; ta ọfà rẹ kí ó sì dà wọ́n rú. Na ọwọ́ rẹ sílẹ̀ láti ibi gíga; gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewu kúrò nínú omi ńlá: kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì. Ẹnu ẹni tí ó kún fún èké ẹni tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ jẹ́ ìrẹ́jẹ.