O. Daf 144

144
Ọpẹ́ fún Ìṣẹ́gun
1OLUBUKÚN li oluwa apata mi, ẹniti o kọ́ ọwọ mi li ogun, ati ika mi ni ìja:
2Õre mi, ati odi-agbara mi; ile-iṣọ giga, ati olugbala mi; asà mi, ati ẹniti mo gbẹkẹle; eniti o tẹri awọn enia mi ba labẹ mi.
3Oluwa, kili enia, ti iwọ fi nkiye si i! tabi ọmọ enia, ti iwọ fi nronú rẹ̀!
4Enia dabi asan: bi ojìji ti nkọja lọ li ọjọ rẹ̀.
5Oluwa, tẹ̀ ọrun rẹ ba, ki o si sọ̀kalẹ: tọ́ awọn òke nla, nwọn o si ru ẽfin.
6Kọ manamana jade, ki o si tú wọn ka: ta ọfà rẹ ki o si dà wọn rú.
7Rán ọwọ rẹ lati òke wá; yọ mi, ki o si gbà mi kuro ninu omi nla, li ọwọ awọn ọmọ àjeji.
8Ẹnu ẹniti nsọ̀rọ asan, ọwọ ọtún wọn si jẹ ọwọ ọtún eke.
9Ọlọrun, emi o kọ orin titun si ọ: lara ohun ọnà orin olokùn mẹwa li emi o kọrin iyìn si ọ.
10On li o nfi igbala fun awọn ọba: ẹniti o gbà Dafidi iranṣẹ rẹ̀ lọwọ idà ipanilara.
11Yọ mi, ki o si gbà mi lọwọ awọn ọmọ àjeji, ẹnu ẹniti nsọ̀rọ asan, ati ọwọ ọtún wọn jẹ ọwọ ọtún eke:
12Ki awọn ọmọkunrin wa, ki o dabi igi gbigbin ti o dagba ni igba-ewe wọn; ki awọn ọmọbinrin wa ki o le dabi ọwọ̀n igun-ile, ti a ṣe lọnà bi afarawe ãfin.
13Ki aká wa ki o le kún, ki o ma funni li oniruru iṣura: ki awọn agutan wa ki o ma bi ẹgbẹgbẹrun ati ẹgbẹgbẹrun mẹwa ni igboro wa:
14Ki awọn malu wa ki o le rẹrù; ki o má si ikọlù, tabi ikolọ jade: ki o má si aroye ni igboro wa.
15Ibukún ni fun awọn enia, ti o mbẹ ni iru ìwa bẹ̃: nitõtọ, ibukún ni fun awọn enia na, ti ẹniti Ọlọrun Oluwa iṣe.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 144: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀