O. Daf 136:1-26

O. Daf 136:1-26 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa: nitoriti o ṣeun; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Ẹ fi ọpẹ fun Ọlọrun awọn ọlọrun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa awọn oluwa: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Fun on nikan ti nṣe iṣẹ iyanu nla: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Fun ẹniti o fi ọgbọ́n da ọrun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Fun ẹniti o tẹ́ ilẹ lori omi: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Fun ẹniti o dá awọn imọlẹ nla: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Õrùn lati jọba ọsan: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai: Oṣupa ati irawọ lati jọba oru: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Fun ẹniti o kọlù Egipti lara awọn akọbi wọn: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. O si mu Israeli jade kuro lãrin wọn: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai: Pẹlu ọwọ agbara, ati apa ninà: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Fun ẹniti o pin Okun pupa ni ìya: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai: O si mu Israeli kọja lọ larin rẹ̀: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Ṣugbọn o bi Farao ati ogun rẹ̀ ṣubu ninu Okun pupa: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Fun ẹniti o sin awọn enia rẹ̀ la aginju ja: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Fun ẹniti o kọlù awọn ọba nla: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. O si pa awọn ọba olokiki: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Sihoni, ọba awọn ara Amori: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Ati Ogu, ọba Baṣani: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. O si fi ilẹ wọn funni ni ini, nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Ini fun Israeli, iranṣẹ rẹ̀; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Ẹniti o ranti wa ni ìwa irẹlẹ wa; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. O si dá wa ni ìde lọwọ awọn ọta wa; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Ẹniti o nfi onjẹ fun ẹda gbogbo: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai; Ẹ fi ọpẹ fun Ọlọrun ọrun; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

O. Daf 136:1-26 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun tí ó ju gbogbo àwọn oriṣa lọ, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA tí ó ju gbogbo àwọn oluwa lọ, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Òun nìkan ṣoṣo ní ń ṣe iṣẹ́ ìyanu ńlá, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lé orí omi, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ó dá oòrùn láti máa ṣe àkóso ọ̀sán, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ó dá òṣùpá ati ìràwọ̀ láti máa ṣe àkóso òru, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹni tí ó pa àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ó sì kó àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò láàrin wọn, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Pẹlu ipá ati ọwọ́ líle ni ó fi kó wọn jáde, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹni tí ó pín Òkun Pupa sí meji, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ó sì mú àwọn ọmọ Israẹli kọjá láàrin rẹ̀, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ṣugbọn ó bi Farao ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ṣubú ninu Òkun Pupa, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹni tí ó mú àwọn eniyan rẹ̀ la aṣálẹ̀ já, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ẹni tí ó pa àwọn ọba ńlá, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ó sì pa àwọn ọba olókìkí, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; Sihoni ọba àwọn Amori, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ati Ogu ọba Baṣani, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ó pín ilẹ̀ wọn fún àwọn eniyan rẹ̀, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ó fún àwọn ọmọ Israẹli, iranṣẹ rẹ̀, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Òun ni ó ranti wa ní ipò ìrẹ̀lẹ̀ wa, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ó sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹni tí ó pèsè oúnjẹ fún gbogbo ẹ̀dá alààyè, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun ọ̀run, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

O. Daf 136:1-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ fi ọpẹ́ fún OLúWA nítorí tí ó ṣeun; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run: nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn olúwa, nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Fún Òun nìkan tí ń ṣiṣẹ́ ìyanu ńlá; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Fún ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Fún ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lórí omi; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Fún ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Òòrùn láti jẹ ọba ọ̀sán; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Òṣùpá àti ìràwọ̀ láti jẹ ọba òru; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Fún ẹni tí ó kọlu Ejibiti lára àwọn àkọ́bí wọn; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Ó sì mú Israẹli jáde kúrò láàrín wọn; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Fún ẹni tí ó pín Òkun pupa ní ìyà; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Ó sì mú Israẹli kọjá láàrín rẹ̀ nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Ṣùgbọ́n ó bi Farao àti ogun rẹ̀ ṣubú nínú Òkun pupa; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Fún ẹni tí ó sin àwọn ènìyàn rẹ̀ la aginjù já nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Fún ẹni tí ó kọlu àwọn ọba ńlá; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Ó sì pa àwọn ọba olókìkí nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Sihoni, ọba àwọn ará Amori nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Àti Ogu, ọba Baṣani; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní, nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Ìní fún Israẹli, ìránṣẹ́ rẹ̀, nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Ẹni tí ó rántí wa ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wa; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Ó sì dá wa ní ìdè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Ẹni tí ó fi oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá gbogbo nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọ̀run; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.