O. Daf 136

136
Orin Ọpẹ́
1Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa: nitoriti o ṣeun; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
2Ẹ fi ọpẹ fun Ọlọrun awọn ọlọrun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
3Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa awọn oluwa: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
4Fun on nikan ti nṣe iṣẹ iyanu nla: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
5Fun ẹniti o fi ọgbọ́n da ọrun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
6Fun ẹniti o tẹ́ ilẹ lori omi: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
7Fun ẹniti o dá awọn imọlẹ nla: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
8Õrùn lati jọba ọsan: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai:
9Oṣupa ati irawọ lati jọba oru: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
10Fun ẹniti o kọlù Egipti lara awọn akọbi wọn: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
11O si mu Israeli jade kuro lãrin wọn: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai:
12Pẹlu ọwọ agbara, ati apa ninà: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
13Fun ẹniti o pin Okun pupa ni ìya: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai:
14O si mu Israeli kọja lọ larin rẹ̀: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
15Ṣugbọn o bi Farao ati ogun rẹ̀ ṣubu ninu Okun pupa: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
16Fun ẹniti o sin awọn enia rẹ̀ la aginju ja: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
17Fun ẹniti o kọlù awọn ọba nla: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
18O si pa awọn ọba olokiki: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
19Sihoni, ọba awọn ara Amori: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
20Ati Ogu, ọba Baṣani: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
21O si fi ilẹ wọn funni ni ini, nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
22Ini fun Israeli, iranṣẹ rẹ̀; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
23Ẹniti o ranti wa ni ìwa irẹlẹ wa; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
24O si dá wa ni ìde lọwọ awọn ọta wa; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
25Ẹniti o nfi onjẹ fun ẹda gbogbo: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai;
26Ẹ fi ọpẹ fun Ọlọrun ọrun; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 136: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀