ORIN DAFIDI 136

136
Orin Ọpẹ́
1Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.#1Kron 16:34; 2Kron 5:13; 7:3; Ẹsr 3:11; O. Daf 100:5; 106:1; 107:1; 118:1; Jer 33:11
2Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun tí ó ju gbogbo àwọn oriṣa lọ,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
3Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA tí ó ju gbogbo àwọn oluwa lọ,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
4Òun nìkan ṣoṣo ní ń ṣe iṣẹ́ ìyanu ńlá,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
5Ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;#Jẹn 1:1
6ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lé orí omi,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;#Jẹn 1:2
7ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá,#136:7 Oòrùn ati òṣùpá.
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
8Ó dá oòrùn láti máa ṣe àkóso ọ̀sán,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
9Ó dá òṣùpá ati ìràwọ̀ láti máa ṣe àkóso òru,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.#Jẹn 1:16
10Ẹni tí ó pa àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;#Eks 12:29
11ó sì kó àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò láàrin wọn,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.#Eks 12:51
12Pẹlu ipá ati ọwọ́ líle ni ó fi kó wọn jáde,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
13Ẹni tí ó pín Òkun Pupa sí meji,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;
14ó sì mú àwọn ọmọ Israẹli kọjá láàrin rẹ̀,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;
15ṣugbọn ó bi Farao ati àwọn ọmọ ogun
rẹ̀ ṣubú ninu Òkun Pupa,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.#Eks 14:21-29
16Ẹni tí ó mú àwọn eniyan rẹ̀ la aṣálẹ̀ já,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;
17ẹni tí ó pa àwọn ọba ńlá,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;
18ó sì pa àwọn ọba olókìkí,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;
19Sihoni ọba àwọn Amori,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;#Nọm 21:21-30
20ati Ogu ọba Baṣani,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.#Nọm 21:31-35
21Ó pín ilẹ̀ wọn fún àwọn eniyan rẹ̀,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;
22ó fún àwọn ọmọ Israẹli, iranṣẹ rẹ̀,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
23Òun ni ó ranti wa ní ipò ìrẹ̀lẹ̀ wa,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;
24ó sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
25Ẹni tí ó pèsè oúnjẹ fún gbogbo ẹ̀dá alààyè,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
26Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun ọ̀run,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 136: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀