ORIN DAFIDI 136:1-26

ORIN DAFIDI 136:1-26 YCE

Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun tí ó ju gbogbo àwọn oriṣa lọ, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA tí ó ju gbogbo àwọn oluwa lọ, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Òun nìkan ṣoṣo ní ń ṣe iṣẹ́ ìyanu ńlá, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lé orí omi, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ó dá oòrùn láti máa ṣe àkóso ọ̀sán, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ó dá òṣùpá ati ìràwọ̀ láti máa ṣe àkóso òru, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹni tí ó pa àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ó sì kó àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò láàrin wọn, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Pẹlu ipá ati ọwọ́ líle ni ó fi kó wọn jáde, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹni tí ó pín Òkun Pupa sí meji, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ó sì mú àwọn ọmọ Israẹli kọjá láàrin rẹ̀, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ṣugbọn ó bi Farao ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ṣubú ninu Òkun Pupa, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹni tí ó mú àwọn eniyan rẹ̀ la aṣálẹ̀ já, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ẹni tí ó pa àwọn ọba ńlá, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ó sì pa àwọn ọba olókìkí, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; Sihoni ọba àwọn Amori, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ati Ogu ọba Baṣani, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ó pín ilẹ̀ wọn fún àwọn eniyan rẹ̀, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ó fún àwọn ọmọ Israẹli, iranṣẹ rẹ̀, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Òun ni ó ranti wa ní ipò ìrẹ̀lẹ̀ wa, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae; ó sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹni tí ó pèsè oúnjẹ fún gbogbo ẹ̀dá alààyè, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun ọ̀run, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú ORIN DAFIDI 136:1-26