Owe 8:27-32
Owe 8:27-32 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati o nṣe ipilẹ awọn ọrun, emi wà nibẹ: nigbati o fi oṣuwọn ayika le oju ọgbun. Nigbati o sọ awọsanma lọjọ̀ soke: nigbati o fi agbara fun orisun ibu: Nigbati o fi aṣẹ rẹ̀ fun okun, ki omi rẹ̀ ki o máṣe kọja ẹnu rẹ̀: ati ofin rẹ̀ fun ipilẹ aiye. Nigbana, emi wà lọdọ rẹ̀, bi oniṣẹ: emi si jẹ didùn-inu rẹ̀ lojojumọ, emi nyọ̀ nigbagbogbo niwaju rẹ̀; Emi nyọ̀ ni ibi-itẹdo aiye rẹ̀: didùn-inu mi si wà sipa awọn ọmọ enia. Njẹ nisisiyi, ẹ fetisi temi, ẹnyin ọmọ: nitoripe ibukún ni fun awọn ti o tẹle ọ̀na mi
Owe 8:27-32 Yoruba Bible (YCE)
Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó dá ojú ọ̀run sí ààyè rẹ̀, tí ó ṣe àmì bìrìkìtì sórí ibú, ní ibi tí ó dàbí ẹni pé ilẹ̀ ati ọ̀run ti pàdé, nígbà tí ó ṣe awọsanma lọ́jọ̀, tí ó fi ìpìlẹ̀ orísun omi sọ ilẹ̀, nígbà tí ó pààlà sí ibi tí òkun gbọdọ̀ kọjá, kí omi má baà kọjá ààyè rẹ̀. Nígbà tí ó sàmì sí ibi tí ìpìlẹ̀ ayé wà, èmi ni oníṣẹ́ ọnà tí mo wà lọ́dọ̀ rẹ̀, Inú mi a máa dùn lojoojumọ, èmi a sì máa yọ̀ níwájú rẹ̀ nígbà gbogbo. Mo láyọ̀ ninu ayé tí àwọn ẹ̀dá alààyè ń gbé, inú mi sì ń dùn sí àwọn ọmọ eniyan. “Nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ fetí sí mi, ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà mi.
Owe 8:27-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn, nígbà tí ó fi òṣùwọ̀n àyíká sórí ibú omi, Nígbà tí ó ṣẹ̀dá òfúrufú lókè tí ó sì fi orísun ibú omi sí ipò rẹ̀ láì le è yẹsẹ̀, Nígbà tí ó ṣe ààlà fún omi Òkun kí omi má ba à kọjá ààlà àṣẹ rẹ̀, àti nígbà tí ó pààlà ìpìlẹ̀ ayé. Nígbà náà èmi ni gbẹ́nàgbẹ́nà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mo kún fún inú dídùn lójoojúmọ́, mo ń yọ̀ nígbà gbogbo níwájú rẹ̀. Mo ń yọ̀ nínú gbogbo àgbáyé tí ó dá mo sì ní inú dídùn sí àwọn ọmọ ènìyàn. “Nítorí náà báyìí, ẹ̀yin ọmọ mi, ìbùkún ni fún àwọn tí ó pa ọ̀nà mi mọ́