Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó dá ojú ọ̀run sí ààyè rẹ̀, tí ó ṣe àmì bìrìkìtì sórí ibú, ní ibi tí ó dàbí ẹni pé ilẹ̀ ati ọ̀run ti pàdé, nígbà tí ó ṣe awọsanma lọ́jọ̀, tí ó fi ìpìlẹ̀ orísun omi sọ ilẹ̀, nígbà tí ó pààlà sí ibi tí òkun gbọdọ̀ kọjá, kí omi má baà kọjá ààyè rẹ̀. Nígbà tí ó sàmì sí ibi tí ìpìlẹ̀ ayé wà, èmi ni oníṣẹ́ ọnà tí mo wà lọ́dọ̀ rẹ̀, Inú mi a máa dùn lojoojumọ, èmi a sì máa yọ̀ níwájú rẹ̀ nígbà gbogbo. Mo láyọ̀ ninu ayé tí àwọn ẹ̀dá alààyè ń gbé, inú mi sì ń dùn sí àwọn ọmọ eniyan. “Nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ fetí sí mi, ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà mi.
Kà ÌWÉ ÒWE 8
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ÌWÉ ÒWE 8:27-32
7 Awọn ọjọ
Ọgbọn lati Ọrun jẹ ẹbùn Ọlọrun fún wà láti mọ ohun to jẹ ti Ọlọ́run to tọ ati òhún ti o tọ, níní oyè wọn ati gbígbé nípa wọn bi ofin. A ngbe nínú ayé tó kún fún ètò, ayineke, àrékérekè, irọ ati etekete satani, báwò ni wa ṣe lá gbogbo èyí já láì sí Ọgbọn Ọlọrun? Oba Solomoni lẹyin gbogbo ànfàní Ọrọ, Owo, Okiki, Ìmọ, ati irin re nínú itura ayé, ṣe àkòtàn Ọgbọn bi "ìbẹrù Olùwà"
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò