Job 31:26-28
Job 31:26-28 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi mo ba bojuwo õrùn nigbati nràn, tabi òṣupa ti nrin ninu itan-imọlẹ, Ti aiya mi si di titan, lati fi ẹnu mi kò ọwọ mi: Eyi pẹlu li ẹ̀ṣẹ ìṣẹniṣẹ lọdọ awọn onidajọ, nitoripe emi iba sẹ́ Ọlọrun ti o wà loke.
Pín
Kà Job 31Job 31:26-28 Yoruba Bible (YCE)
Tí mo bá ti wo oòrùn nígbà tí ó ń ràn, tabi tí mo wo òṣùpá ninu ẹwà rẹ̀: tí ọkàn mi fà sí wọn; tí mo sì tẹ́wọ́ adura sí wọn. Èyí pẹlu yóo jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, tí adájọ́ gbọdọ̀ jẹ mí níyà fún; nítorí yóo jẹ́ aiṣootọ sí Ọlọrun ọ̀run.
Pín
Kà Job 31Job 31:26-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí mo bá bojú wo oòrùn nígbà tí ń ràn, tàbí òṣùpá tí ń ràn nínú ìtànmọ́lẹ̀, Bí a bá tàn ọkàn mi jẹ: Láti fi ẹnu mi kò ọwọ́ mi: Èyí pẹ̀lú ni ẹ̀ṣẹ̀ ti àwọn onídàájọ́ ní láti bẹ̀wò. Nítorí pé èmí yóò jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run tí ó wà lókè.
Pín
Kà Job 31