Job 31

31
1EMI ti bá oju mi da majẹmu, njẹ emi o ha ṣe tẹjumọ wundia?
2Nitoripe kini ipin Ọlọrun lati ọrun wá, tabi kini ogún Olodumare lati oke ọrun wá?
3Kò ṣepe awọn enia buburu ni iparun wà fun, ati ìṣẹniṣẹ fun awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ?
4On kò ha ri ipa-ọ̀na mi, on kò ha si ka gbogbo iṣiṣe mi?
5Bi o ba ṣepe emi ba fi aiṣotitọ rìn, tabi ti ẹsẹ mi si yara si ẹ̀tan.
6Ki a diwọn mi ninu iwọ̀n ododo, ki Ọlọrun le imọ̀ iduroṣinṣin mi.
7Bi ẹsẹ mi ba yà kuro loju ọ̀na, ti aiya mi si tẹ̀le ipa oju mi, bi àbawọn kan ba si lẹmọ́ mi li ọwọ.
8Njẹ ki emi ki o gbìn ki ẹlomiran ki o si mu u jẹ, ani ki a fà iru-ọmọ mi tu.
9Bi aiya mi ba di fifa sipasẹ obinrin kan, tabi bi mo ba lọ iba deni ni ẹnu-ọ̀na ile aladugbo mi,
10Njẹ ki aya mi ki o lọ ọlọ fun ẹlomiran, ki awọn ẹlomiran ki o tẹ̀ ara wọn li ara rẹ̀.
11Nitoripe ẹ̀ṣẹ buburu li eyi; ani ẹ̀ṣẹ ìṣẹniṣẹ ni lọdọ awọn onidajọ.
12Nitoripe iná ni eyi ti o jo de iparun, ti iba si fà gbongbo ohun ibisi mi gbogbo tu.
13Bi mo ba si ṣe aikà ọ̀ran iranṣẹkunrin mi tabi iranṣẹbinrin mi si, nigbati nwọn ba mba mi jà;
14Kili emi o ha ṣe nigbati Ọlọrun ba dide; nigbati o ba si ṣe ibẹwo, ohùn kili emi o dá?
15Ẹniti o dá mi ni inu kọ li o da a? ẹnikanna ki o mọ wa ni inu?
16Bi mo ba fà ọwọ sẹhin fun ifẹ-inu talaka, tabi bi mo ba si mu oju opó mofo;
17Tabi ti mo ba nikan bu òkele mi jẹ, ti alainibaba kò jẹ ninu rẹ̀;
18Nitoripe lati igba ewe mi wá li a ti tọ́ ọ dàgba pẹlu mi bi ẹnipe baba, emi si nṣe itọju rẹ̀ (opó) lati inu iya mi wá.
19Bi emi ba ri olupọnju laini aṣọ, tabi talaka kan laini ibora;
20Bi ẹgbẹ rẹ̀ kò ba sure fun mi, tabi bi ara rẹ̀ kò si gbona nipasẹ irun agutan mi.
21Bi mo ba si gbe ọwọ mi soke si alainibaba, nitoripe mo ri iranlọwọ mi li ẹnu-bode,
22Njẹ ki apá mi ki o wọ́n kuro li ọkọ́ ejika rẹ̀, ki apá mi ki o si ṣẹ́ lati egungun rẹ̀ wá.
23Nitoripe iparun lati ọdọ Ọlọrun wá ni ẹ̀ru-nla fun mi, ati nitori Ọlanla rẹ̀ emi kò le iduro.
24Bi o ba ṣepe mo fi wura ṣe igbẹkẹle mi, tabi bi mo ba wi fun wura didara pe, iwọ ni igbẹkẹle mi;
25Bi mo ba yọ̀ nitori ọrọ̀ mi pọ̀, ati nitori ọwọ mi dẹ̀ lọpọlọpọ;
26Bi mo ba bojuwo õrùn nigbati nràn, tabi òṣupa ti nrin ninu itan-imọlẹ,
27Ti aiya mi si di titan, lati fi ẹnu mi kò ọwọ mi:
28Eyi pẹlu li ẹ̀ṣẹ ìṣẹniṣẹ lọdọ awọn onidajọ, nitoripe emi iba sẹ́ Ọlọrun ti o wà loke.
29Bi o ba ṣepe mo yọ̀ si iparun ẹniti o korira mi, tabi bi mo ba si gbera soke, nigbati ibi bá a.
30Bẹ̃li emi kò si jẹ ki ẹnu mi ki o ṣẹ̀ nipa fifẹ egún si ọkàn rẹ̀.
31Bi awọn enia inu agọ mi kò ba le wipe, Tali o le ri ẹniti agbo-ẹran rẹ̀ kò tẹlọrùn?
32Alejo kò wọ̀ ni igboro ri, emi ṣi ilẹkun mi silẹ fun èro.
33Bi mo ba bò irekọja mi mọlẹ bi Adamu, ni pipa ẹbi mi mọ́ li aiya mi:
34Ọ̀pọlọpọ enia ni mo ha bẹ̀ru bi, tabi ẹ̀gan awọn idile ni mba mi li ẹ̀ru? ti mo fi pa ẹnu mọ́, ti emi kò si fi jade sode?
35Ibaṣepe ẹnikan le gbọ́ ti emi! kiyesi i, àmi mi! ki Olodumare ki o da mi lohùn! ki emi ki o si ri iwe na ti ọta mi ti kọ!
36Nitõtọ emi iba gbe e le ejika mi, emi iba si dì i bi ade mọ́ ori mi.
37Emi iba si sọ iye ìṣisẹ mi fun u, bi ọmọ-alade li emi iba sunmọ ọdọ rẹ̀.
38Bi ilẹ mi ba si ke fi mi sùn, tabi ti aporo rẹ̀ pẹlu si sọkun,
39Bi mo ba jẹ eso oko mi lainawo si i, tabi ti mo si mu ọkàn oluwa rẹ̀ fò lọ,
40Ki ẹgun òṣuṣu ki o hù nipo alikama, ati wèpe nipo ọka-bàba. (Ọ̀rọ Jobu pari.)

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Job 31: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa