JOBU 31

31
1“Mo ti bá ojú mi dá majẹmu;
n óo ṣe wá máa wo wundia?
2Kí ni yóo jẹ́ ìpín mi lọ́dọ̀ Ọlọrun lókè?
Kí ni ogún mi lọ́dọ̀ Olodumare?
3Ṣebí jamba a máa bá àwọn alaiṣododo,
àjálù a sì máa dé bá àwọn oníṣẹ́-ẹ̀ṣẹ̀.
4Ṣebí Ọlọrun mọ ọ̀nà mi,
ó sì mọ ìrìn mi.
5Bí mo bá rìn ní ọ̀nà aiṣododo,
tí mo sì yára láti sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn,
6(kí Ọlọrun gbé mi ka orí ìwọ̀n tòótọ́,
yóo sì rí i pé olóòótọ́ ni mí!)
7Bí mo bá ti yí ẹsẹ̀ kúrò ní ọ̀nà tààrà,
tí mò ń ṣe ojúkòkòrò,
tí ọwọ́ mi kò sì mọ́,
8jẹ́ kí ẹlòmíràn kórè oko mi,
kí o sì fa ohun ọ̀gbìn mi tu.
9“Bí ọkàn mi bá fà sí obinrin olobinrin,
tabi kí n máa pẹ́ kọ̀rọ̀ lẹ́nu ọ̀nà aládùúgbò mi;
10jẹ́ kí iyawo mi máa se oúnjẹ fún ẹlòmíràn,
kí ẹlòmíràn sì máa bá a lòpọ̀.
11Nítorí ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó burú jù,
ẹ̀ṣẹ̀ tí adájọ́ gbọdọ̀ jẹ mí níyà fún.
12Iná ajónirun ni,
tí yóo run gbogbo ohun ìní mi kanlẹ̀.
13“Bí mo bá kọ̀ láti fetí sí ẹjọ́ àwọn
iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin mi,
nígbà tí wọ́n bá fẹ̀sùn kàn mí,
14báwo ni n óo ṣe dúró níwájú Ọlọrun?
Kí ni kí n wí nígbà tí ó bá bèèrè lọ́wọ́ mi?
15Ṣebí ẹni tí ó dá mi ninu oyún,
òun kan náà ló dá iranṣẹ mi?
Òun ló mọ wá kí wọn tó bí wa.
16“Bí mo bá fi ohunkohun pọ́n talaka lójú rí,
tabi kí n fi opó sílẹ̀ ninu àìní,
17tabi kí n dá oúnjẹ mi jẹ,
láìfún ọmọ aláìníbaba jẹ
18(láti ìgbà èwe rẹ̀ ni mo ti ń ṣe bíi baba fún un,
tí mo sì ń tọ́jú rẹ̀ láti inú ìyá rẹ̀);#Tob 4:7-11, 16
19bí mo bá ti rí ẹni tí ó ń kú lọ,
nítorí àìrí aṣọ bora,
tabi talaka tí kò rí ẹ̀wù wọ̀,
20kí ó sì súre fún mi,
nítorí pé ara rẹ̀ móoru
pẹlu aṣọ tí a fi irun aguntan mi hun,
21bí mo bá fi ìyà jẹ aláìníbaba,
nítorí pé mo mọ eniyan ní ilé ẹjọ́,
22jẹ́ kí apá mi já kúrò léjìká mi,
kí ó yọ ní oríkèé rẹ̀.
23Nítorí ẹ̀rù ìpọ́njú láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ń bà mí,
nítorí ògo rẹ̀, n kò lè dán irú rẹ̀ wò.
24“Bí mo bá gbójú lé wúrà,
tí mo sì fi ojúlówó wúrà ṣe igbẹkẹle mi,
25bí mo bá ń yọ̀ nítorí pé mo ní ọrọ̀ pupọ,
tabi nítorí pé ọwọ́ mi ti ba ọpọlọpọ ohun ìní.
26Tí mo bá ti wo oòrùn nígbà tí ó ń ràn,
tabi tí mo wo òṣùpá ninu ẹwà rẹ̀:
27tí ọkàn mi fà sí wọn;
tí mo sì tẹ́wọ́ adura sí wọn.
28Èyí pẹlu yóo jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,
tí adájọ́ gbọdọ̀ jẹ mí níyà fún;
nítorí yóo jẹ́ aiṣootọ sí Ọlọrun ọ̀run.#Sir 31:5-10
29“Bí mo bá yọ̀ nítorí ìparun ẹni tí ó kórìíra mi,
tabi kí inú mi dùn nígbà tí ohun burúkú bá ṣẹlẹ̀ sí i.
30(N kò fi ẹnu mi ṣẹ̀
kí n gbé e ṣépè pé kí ó lè kú);
31bí àwọn tí wọn ń gbé inú àgọ́ mi kò bá wí pé,
‘Ta ló kù tí kò tíì yó?’
32(Kò sí àlejò tí ń sun ìta gbangba,
nítorí ìlẹ̀kùn ilé mi ṣí sílẹ̀ fún àwọn arìnrìnàjò);
33bí mo bá fi ẹ̀ṣẹ̀ mi pamọ́ fún eniyan,
tí mo sì dé àìdára mi mọ́ra,
34nítorí pé mò ń bẹ̀rù ọpọlọpọ eniyan,
ẹ̀gàn ìdílé sì ń dẹ́rùbà mí,
tóbẹ́ẹ̀ tí mo fi dákẹ́, tí n kò sì jáde síta.
35Ha! Ǹ bá rí ẹni gbọ́ tèmi!
(Mo ti tọwọ́ bọ̀wé,
kí Olodumare dá mi lóhùn!)
Ǹ bá lè ní àkọsílẹ̀ ẹ̀sùn tí àwọn ọ̀tá fi kàn mí!
36Dájúdájú, ǹ bá gbé e lé èjìká mi,
ǹ bá fi dé orí bí adé;
37ǹ bá sọ gbogbo ìgbésẹ̀ mi fún Ọlọrun,
ǹ bá bá a sọ̀rọ̀ bí ìjòyè.
38“Bí ilẹ̀ mi bá kígbe ẹ̀san lé mi lórí,
tí àwọn poro oko mi sì ń sọkún;
39tí mo bá jẹ ninu ìkórè ilẹ̀ náà láìsanwó rẹ̀,
tabi tí mo sì ṣe ikú pa ẹni tí ó ni ín,
40kí ẹ̀gún hù lórí ilẹ̀ náà dípò ọkà,
kí koríko hù dípò ọkà baali.”
Ọ̀rọ̀ Jobu parí síhìn-ín.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JOBU 31: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀