Deu 1:20-40

Deu 1:20-40 Bibeli Mimọ (YBCV)

Emi si wi fun nyin pe, Ẹnyin dé òke awọn ọmọ Amori na, ti OLUWA Ọlọrun wa fi fun wa. Wò o, OLUWA Ọlọrun rẹ ti fi ilẹ na siwaju rẹ: gòke lọ, ki o si gbà a, bi OLUWA, Ọlọrun awọn baba rẹ ti wi fun ọ; máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àiya máṣe fò ọ. Gbogbo nyin si tọ̀ mi wá, ẹ si wipe, Jẹ ki awa ki o rán enia lọ siwaju wa, ki nwọn ki o si rìn ilẹ na wò fun wa, ki nwọn ki o si mú ìhin pada tọ̀ wa wá, niti ọ̀na ti a o ba gòke lọ, ati ti ilu ti a o yọ si. Ọ̀rọ na si dara loju mi: mo si yàn ọkunrin mejila ninu nyin, ẹnikan ninu ẹ̀ya kan: Nwọn si yipada nwọn si lọ sori òke, nwọn si wá si afonifoji Eṣkolù, nwọn si rìn ilẹ na wò. Nwọn si mú ninu eso ilẹ na li ọwọ́ wọn, nwọn si mú u sọkalẹ wá fun wa, nwọn si mú ìhin pada wá fun wa, nwọn si wipe, Ilẹ ti OLUWA wa fi fun wa, ilẹ rere ni. Ṣugbọn ẹnyin kò fẹ́ gòke lọ, ẹnyin si ṣọ̀tẹ si aṣẹ OLUWA Ọlọrun nyin: Ẹnyin si kùn ninu agọ́ nyin, wipe, Nitoriti OLUWA korira wa, li o ṣe mú wa lati Egipti jade wá, lati fi wa lé ọwọ́ awọn ọmọ Amori, lati run wa. Nibo li awa o gbé gòke lọ? awọn arakunrin wa ti daiyajá wa, wipe, Awọn enia na sigbọnlẹ jù wa lọ; ilu wọn tobi a si mọdi wọn kan ọrun; pẹlupẹlu awa ri awọn ọmọ Anaki nibẹ̀. Nigbana ni mo wi fun nyin pe, Ẹ máṣe fòya, bẹ̃ni ki ẹ máṣe bẹ̀ru wọn. OLUWA Ọlọrun nyin ti nṣaju nyin, on ni yio jà fun nyin, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe fun nyin ni Egipti li oju nyin; Ati li aginjù, nibiti iwọ ri bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti gbé ọ, bi ọkunrin ti igbé ọmọ rẹ̀, li ọ̀na nyin gbogbo ti ẹnyin rìn, titi ẹnyin fi dé ihinyi. Sibẹ̀ ninu nkan yi ẹnyin kò gbà OLUWA Ọlọrun nyin gbọ́. Ti nlọ li ọ̀na ṣaju nyin, lati wá ibi fun nyin, ti ẹnyin o pagọ́ nyin si, ninu iná li oru, lati fi ọ̀na ti ẹnyin o gbà hàn nyin, ati ninu awọsanma li ọsán. OLUWA si gbọ́ ohùn ọ̀rọ nyin, o si binu, o si bura, wipe, Nitõtọ ọkan ninu awọn ọkunrin wọnyi ti iran buburu yi, ki yio ri ilẹ rere na, ti mo ti bura lati fi fun awọn baba nyin, Bikoṣe Kalebu ọmọ Jefunne, on ni yio ri i; on li emi o fi ilẹ na ti o tẹ̀mọlẹ fun, ati fun awọn ọmọ rẹ̀: nitoriti o tẹle OLUWA lẹhin patapata. OLUWA si binu si mi pẹlu nitori nyin, wipe, Iwọ pẹlu ki yio dé ibẹ̀: Joṣua ọmọ Nuni, ti ima duro niwaju rẹ, on ni yio dé ibẹ̀: gbà a ni iyanju; nitoripe on ni yio mu Israeli ní i. Ati awọn ọmọ wẹ́wẹ nyin, ti ẹnyin wipe nwọn o di ijẹ, ati awọn ọmọ nyin, ti nwọn kò mọ̀ rere tabi buburu loni yi, awọn ni o dé ibẹ̀, awọn li emi o si fi i fun, awọn ni yio si ní i. Ṣugbọn bi o ṣe ti nyin ni, ẹ pada, ẹ mú ọ̀na nyin pọ̀n lọ si aginjù li ọ̀na Okun Pupa.

Deu 1:20-40 Yoruba Bible (YCE)

Mo sọ fun yín nígbà náà pé, ẹ ti dé agbègbè olókè àwọn ará Amori, tí OLUWA Ọlọrun wa fi fún wa, ilẹ̀ náà ni OLUWA Ọlọrun yín tẹ́ kalẹ̀ níwájú yín yìí, mo ní kí ẹ gbéra, kí ẹ lọ gbà á, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun àwọn baba ńlá yín ti sọ fun yín. Mo ní kí ẹ má bẹ̀rù rárá, kí ẹ má sì fòyà. “Gbogbo yín wá sọ́dọ̀ mi, ẹ sì wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á rán àwọn eniyan lọ ṣiwaju wa, láti lọ ṣe amí ilẹ̀ náà, kí wọ́n lè wá jábọ̀ fún wa, kí á lè mọ ọ̀nà tí ó yẹ kí á tọ̀, ati àwọn ìlú tí ó yẹ kí á wọ̀.’ “Ọ̀rọ̀ yín dára lójú mi, mo sì yan ọkunrin mejila láàrin yín, ọkunrin kọ̀ọ̀kan láàrin ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Wọ́n gbéra, wọ́n lọ sí agbègbè olókè náà, títí tí wọ́n fi dé àfonífojì Eṣikolu, tí wọ́n sì ṣe amí rẹ̀. Wọ́n ká ninu èso ilẹ̀ náà bọ̀, wọ́n sì jábọ̀ fún wa pé ilẹ̀ dáradára ni OLUWA Ọlọrun wa fi fún wa. “Sibẹsibẹ, ẹ kọ̀, ẹ kò lọ, ẹ ṣe orí kunkun sí àṣẹ tí OLUWA Ọlọrun yín pa fun yín. Ẹ bẹ̀rẹ̀ sí kùn ninu àgọ́ yín, ẹ ní, ‘Ọlọrun kò fẹ́ràn wa, ni ó ṣe kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti, kí ó lè kó wa lé àwọn ará Amori lọ́wọ́, kí wọ́n sì pa wá run. Kí ni a fẹ́ lọ ṣe níbẹ̀? Ojora ti mú wa, nítorí ọ̀rọ̀ tí àwọn arakunrin wa sọ fún wa, tí wọ́n ní àwọn ará ibẹ̀ lágbára jù wá lọ, wọ́n sì ṣígbọnlẹ̀ jù wá lọ. Àwọn ìlú wọn tóbi, wọ́n sì jẹ́ ìlú olódi, odi wọn ga kan ọ̀run, àwọn òmìrán ọmọ Anaki sì wà níbẹ̀!’ “Mo wí fun yín nígbà náà pé kí ẹ má ṣojo, kí ẹ má sì jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà yín. OLUWA Ọlọrun yín tí ń ṣáájú yín ni yóo jà fun yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti jà fun yín ní ilẹ̀ Ijipti, tí ẹ̀yin náà sì fi ojú ara yín rí i. Ninu aṣálẹ̀ ńkọ́? Ṣebí ẹ rí i bí OLUWA Ọlọrun yín ti gbé yín, bí baba tíí gbé ọmọ rẹ̀, ní gbogbo ọ̀nà tí ẹ tọ̀ títí tí ẹ fi dé ibi tí ẹ wà yìí. Sibẹsibẹ ẹ kò gba OLUWA Ọlọrun yín gbọ́, Ọlọrun tí ń lọ níwájú yín ninu ọ̀wọ̀n iná lóru, ati ninu ìkùukùu lọ́sàn-án, láti fi ọ̀nà tí ẹ óo máa tọ̀ hàn yín kí ó lè bá yín wá ibi tí ẹ óo pàgọ́ yín sí. “OLUWA gbọ́ ohun tí ẹ sọ, inú bí i, ó sì búra pé, ẹnikẹ́ni ninu ìran burúkú náà kò ní fi ojú kan ilẹ̀ dáradára tí òun ti búra pé òun óo fún àwọn baba yín; àfi Kalebu ọmọ Jefune ni yóo rí i. Òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni òun óo sì fún ní ilẹ̀ tí ó ti fi ẹsẹ̀ rẹ̀ tẹ̀, nítorí pé, ó fi tọkàntọkàn tẹ̀lé òun. OLUWA bínú sí èmi pàápàá nítorí tiyín, ó ní èmi náà kò ní dé ibẹ̀. Joṣua, ọmọ Nuni, tí ń ṣe iranṣẹ òun, ni yóo dé ilẹ̀ náà. Nítorí náà, ó ní kí n mú un lọ́kàn le, nítorí òun ni yóo jẹ́ kí Israẹli gba ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì jogún rẹ̀. Ọlọrun ní àwọn ọmọ yín kéékèèké, tí kò tíì mọ ire yàtọ̀ sí ibi, àwọn tí ẹ sọ pé wọn yóo bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín, àwọn ni wọn yóo dé ilẹ̀ náà, àwọn ni òun óo sì fi fún, ilẹ̀ náà yóo sì di ìní wọn. Ṣugbọn ní tiyín, ó ní kí ẹ yipada, kí ẹ sì máa lọ sinu aṣálẹ̀, ní apá ọ̀nà Òkun Pupa.

Deu 1:20-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà náà ni mo sọ fún un yín pé, “Ẹ ti dé ilẹ̀ òkè àwọn ará Amori, èyí tí OLúWA Ọlọ́run wa fún wa. Ẹ kíyèsi i, OLúWA Ọlọ́run yín ló ni ilẹ̀ náà. Ẹ lọ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà bí OLúWA Ọlọ́run àwọn baba yín tí sọ fún un yín. Ẹ má bẹ̀rù, Ẹ má sì ṣe fòyà.” Nígbà náà ni gbogbo yín tọ̀ mí wá wí pé, “Jẹ́ kí a yan àwọn ayọ́lẹ̀wò láti yọ́ ilẹ̀ náà wò fún wa, kí wọn sì fún wa ní ìròyìn àwọn ọ̀nà tí a ó gbà àti àwọn ìlú tí a ó bá pàdé.” Èrò náà sì dára lójú mi, torí èyí ni mo ṣe yan àwọn ènìyàn méjìlá nínú yín, ẹnìkan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Wọ́n sì gòkè lọ sí ilẹ̀ òkè náà, wọ́n sì wá sí Àfonífojì Eṣkolu, wọ́n sì yẹ̀ ẹ́ wò. Wọ́n sì mú lára èso ilẹ̀ náà wá fún wa pé, “Ilẹ̀ tí ó dára ni OLúWA Ọlọ́run wa fún wa.” OLúWA Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́ gòkè lọ; ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ OLúWA Ọlọ́run yín. Ẹ kùn nínú àgọ́ ọ yín, ẹ sì wí pé, “OLúWA kórìíra wa, torí èyí ló fi mú wa jáde láti Ejibiti láti fi wá lé àwọn ará Amori lọ́wọ́ láti pa wá run. Níbo la ó lọ? Àwọn arákùnrin wa ti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa nípa sísọ pé, ‘Àwọn ènìyàn náà lágbára wọ́n sì ga jù wá lọ; àwọn ìlú náà tóbi jọjọ bẹ́ẹ̀ ni odi wọn ga kan ọ̀run. A tilẹ̀ rí àwọn òmíràn (ìran Anaki) níbẹ̀.’ ” Nígbà náà ni mo sọ fún un yín pé, “Ẹ má ṣojo, ẹ kò sì gbọdọ̀ bẹ̀rù wọn. OLúWA Ọlọ́run yín, tí ń ṣáájú yín yóò jà fún un yín; bí ó ti ṣe fún un yín ní Ejibiti lójú ẹ̀yin tìkára yín àti ní aginjù. Níbẹ̀ ni ẹ ti rí i bí OLúWA Ọlọ́run yín ti gbé yín, bí baba ti í gbé ọmọ rẹ̀, ní gbogbo ọ̀nà tí ẹ lọ títí ẹ fi padà dé ibí yìí.” Pẹ̀lú gbogbo èyí tí mo wí, ẹ kò gbẹ́kẹ̀lé OLúWA Ọlọ́run yín, tí ń ṣáájú u yín lọ ní gbogbo ọ̀nà yín, nípa fífi iná ṣe amọ̀nà yín ní òru àti ìkùùkuu ní ọ̀sán, láti fi àwọn ibi tí ẹ lè tẹ̀dó sí hàn yín àti àwọn ọ̀nà tí ẹ ó rìn. Nígbà tí OLúWA gbọ́ ohun tí ẹ sọ, inú bí i, ó sì búra wí pé: “Kò sí ọ̀kan nínú ìran búburú yìí tí yóò dé ilẹ̀ rere tí mo ti búra láti fún àwọn baba ńlá a yín. Bí kò ṣe Kalebu ọmọ Jefunne. Òun ni yóò wọ̀ ọ́. Èmi yóò sì fún òun àti àwọn ìran rẹ̀ ní ilẹ̀ náà tí ó ti fi ẹsẹ̀ rẹ̀ tẹ̀; torí pé ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀lé OLúWA.” Torí i tiyín ni OLúWA fi bínú sí mi wí pé, “Ìwọ náà kì yóò wọ ibẹ̀ bákan náà, ṣùgbọ́n Joṣua ọmọ Nuni tí ń ṣe olùrànlọ́wọ́ rẹ ni yóò wọ ibẹ̀. Mú un, ní ọkàn le torí pé, òun yóò ṣáájú àwọn ọmọ Israẹli láti gba ilẹ̀ náà. Àwọn èwe yín tí ẹ sọ pé wọn yóò kó lẹ́rú. Àwọn ọmọ yín tí ko tí ì mọ rere yàtọ̀ sí búburú ni yóò wọ ilẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, ẹ yí padà sí aginjù tí ó wà ní ọ̀nà tí ó lọ sí Òkun pupa.”