Emi si wi fun nyin pe, Ẹnyin dé òke awọn ọmọ Amori na, ti OLUWA Ọlọrun wa fi fun wa.
Wò o, OLUWA Ọlọrun rẹ ti fi ilẹ na siwaju rẹ: gòke lọ, ki o si gbà a, bi OLUWA, Ọlọrun awọn baba rẹ ti wi fun ọ; máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àiya máṣe fò ọ.
Gbogbo nyin si tọ̀ mi wá, ẹ si wipe, Jẹ ki awa ki o rán enia lọ siwaju wa, ki nwọn ki o si rìn ilẹ na wò fun wa, ki nwọn ki o si mú ìhin pada tọ̀ wa wá, niti ọ̀na ti a o ba gòke lọ, ati ti ilu ti a o yọ si.
Ọ̀rọ na si dara loju mi: mo si yàn ọkunrin mejila ninu nyin, ẹnikan ninu ẹ̀ya kan:
Nwọn si yipada nwọn si lọ sori òke, nwọn si wá si afonifoji Eṣkolù, nwọn si rìn ilẹ na wò.
Nwọn si mú ninu eso ilẹ na li ọwọ́ wọn, nwọn si mú u sọkalẹ wá fun wa, nwọn si mú ìhin pada wá fun wa, nwọn si wipe, Ilẹ ti OLUWA wa fi fun wa, ilẹ rere ni.
Ṣugbọn ẹnyin kò fẹ́ gòke lọ, ẹnyin si ṣọ̀tẹ si aṣẹ OLUWA Ọlọrun nyin:
Ẹnyin si kùn ninu agọ́ nyin, wipe, Nitoriti OLUWA korira wa, li o ṣe mú wa lati Egipti jade wá, lati fi wa lé ọwọ́ awọn ọmọ Amori, lati run wa.
Nibo li awa o gbé gòke lọ? awọn arakunrin wa ti daiyajá wa, wipe, Awọn enia na sigbọnlẹ jù wa lọ; ilu wọn tobi a si mọdi wọn kan ọrun; pẹlupẹlu awa ri awọn ọmọ Anaki nibẹ̀.
Nigbana ni mo wi fun nyin pe, Ẹ máṣe fòya, bẹ̃ni ki ẹ máṣe bẹ̀ru wọn.
OLUWA Ọlọrun nyin ti nṣaju nyin, on ni yio jà fun nyin, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe fun nyin ni Egipti li oju nyin;
Ati li aginjù, nibiti iwọ ri bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti gbé ọ, bi ọkunrin ti igbé ọmọ rẹ̀, li ọ̀na nyin gbogbo ti ẹnyin rìn, titi ẹnyin fi dé ihinyi.
Sibẹ̀ ninu nkan yi ẹnyin kò gbà OLUWA Ọlọrun nyin gbọ́.
Ti nlọ li ọ̀na ṣaju nyin, lati wá ibi fun nyin, ti ẹnyin o pagọ́ nyin si, ninu iná li oru, lati fi ọ̀na ti ẹnyin o gbà hàn nyin, ati ninu awọsanma li ọsán.
OLUWA si gbọ́ ohùn ọ̀rọ nyin, o si binu, o si bura, wipe,
Nitõtọ ọkan ninu awọn ọkunrin wọnyi ti iran buburu yi, ki yio ri ilẹ rere na, ti mo ti bura lati fi fun awọn baba nyin,
Bikoṣe Kalebu ọmọ Jefunne, on ni yio ri i; on li emi o fi ilẹ na ti o tẹ̀mọlẹ fun, ati fun awọn ọmọ rẹ̀: nitoriti o tẹle OLUWA lẹhin patapata.
OLUWA si binu si mi pẹlu nitori nyin, wipe, Iwọ pẹlu ki yio dé ibẹ̀:
Joṣua ọmọ Nuni, ti ima duro niwaju rẹ, on ni yio dé ibẹ̀: gbà a ni iyanju; nitoripe on ni yio mu Israeli ní i.
Ati awọn ọmọ wẹ́wẹ nyin, ti ẹnyin wipe nwọn o di ijẹ, ati awọn ọmọ nyin, ti nwọn kò mọ̀ rere tabi buburu loni yi, awọn ni o dé ibẹ̀, awọn li emi o si fi i fun, awọn ni yio si ní i.
Ṣugbọn bi o ṣe ti nyin ni, ẹ pada, ẹ mú ọ̀na nyin pọ̀n lọ si aginjù li ọ̀na Okun Pupa.