Mo sọ fun yín nígbà náà pé, ẹ ti dé agbègbè olókè àwọn ará Amori, tí OLUWA Ọlọrun wa fi fún wa, ilẹ̀ náà ni OLUWA Ọlọrun yín tẹ́ kalẹ̀ níwájú yín yìí, mo ní kí ẹ gbéra, kí ẹ lọ gbà á, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun àwọn baba ńlá yín ti sọ fun yín. Mo ní kí ẹ má bẹ̀rù rárá, kí ẹ má sì fòyà.
“Gbogbo yín wá sọ́dọ̀ mi, ẹ sì wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á rán àwọn eniyan lọ ṣiwaju wa, láti lọ ṣe amí ilẹ̀ náà, kí wọ́n lè wá jábọ̀ fún wa, kí á lè mọ ọ̀nà tí ó yẹ kí á tọ̀, ati àwọn ìlú tí ó yẹ kí á wọ̀.’
“Ọ̀rọ̀ yín dára lójú mi, mo sì yan ọkunrin mejila láàrin yín, ọkunrin kọ̀ọ̀kan láàrin ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Wọ́n gbéra, wọ́n lọ sí agbègbè olókè náà, títí tí wọ́n fi dé àfonífojì Eṣikolu, tí wọ́n sì ṣe amí rẹ̀. Wọ́n ká ninu èso ilẹ̀ náà bọ̀, wọ́n sì jábọ̀ fún wa pé ilẹ̀ dáradára ni OLUWA Ọlọrun wa fi fún wa.
“Sibẹsibẹ, ẹ kọ̀, ẹ kò lọ, ẹ ṣe orí kunkun sí àṣẹ tí OLUWA Ọlọrun yín pa fun yín. Ẹ bẹ̀rẹ̀ sí kùn ninu àgọ́ yín, ẹ ní, ‘Ọlọrun kò fẹ́ràn wa, ni ó ṣe kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti, kí ó lè kó wa lé àwọn ará Amori lọ́wọ́, kí wọ́n sì pa wá run. Kí ni a fẹ́ lọ ṣe níbẹ̀? Ojora ti mú wa, nítorí ọ̀rọ̀ tí àwọn arakunrin wa sọ fún wa, tí wọ́n ní àwọn ará ibẹ̀ lágbára jù wá lọ, wọ́n sì ṣígbọnlẹ̀ jù wá lọ. Àwọn ìlú wọn tóbi, wọ́n sì jẹ́ ìlú olódi, odi wọn ga kan ọ̀run, àwọn òmìrán ọmọ Anaki sì wà níbẹ̀!’
“Mo wí fun yín nígbà náà pé kí ẹ má ṣojo, kí ẹ má sì jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà yín. OLUWA Ọlọrun yín tí ń ṣáájú yín ni yóo jà fun yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti jà fun yín ní ilẹ̀ Ijipti, tí ẹ̀yin náà sì fi ojú ara yín rí i. Ninu aṣálẹ̀ ńkọ́? Ṣebí ẹ rí i bí OLUWA Ọlọrun yín ti gbé yín, bí baba tíí gbé ọmọ rẹ̀, ní gbogbo ọ̀nà tí ẹ tọ̀ títí tí ẹ fi dé ibi tí ẹ wà yìí. Sibẹsibẹ ẹ kò gba OLUWA Ọlọrun yín gbọ́, Ọlọrun tí ń lọ níwájú yín ninu ọ̀wọ̀n iná lóru, ati ninu ìkùukùu lọ́sàn-án, láti fi ọ̀nà tí ẹ óo máa tọ̀ hàn yín kí ó lè bá yín wá ibi tí ẹ óo pàgọ́ yín sí.
“OLUWA gbọ́ ohun tí ẹ sọ, inú bí i, ó sì búra pé, ẹnikẹ́ni ninu ìran burúkú náà kò ní fi ojú kan ilẹ̀ dáradára tí òun ti búra pé òun óo fún àwọn baba yín; àfi Kalebu ọmọ Jefune ni yóo rí i. Òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni òun óo sì fún ní ilẹ̀ tí ó ti fi ẹsẹ̀ rẹ̀ tẹ̀, nítorí pé, ó fi tọkàntọkàn tẹ̀lé òun. OLUWA bínú sí èmi pàápàá nítorí tiyín, ó ní èmi náà kò ní dé ibẹ̀. Joṣua, ọmọ Nuni, tí ń ṣe iranṣẹ òun, ni yóo dé ilẹ̀ náà. Nítorí náà, ó ní kí n mú un lọ́kàn le, nítorí òun ni yóo jẹ́ kí Israẹli gba ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì jogún rẹ̀. Ọlọrun ní àwọn ọmọ yín kéékèèké, tí kò tíì mọ ire yàtọ̀ sí ibi, àwọn tí ẹ sọ pé wọn yóo bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín, àwọn ni wọn yóo dé ilẹ̀ náà, àwọn ni òun óo sì fi fún, ilẹ̀ náà yóo sì di ìní wọn. Ṣugbọn ní tiyín, ó ní kí ẹ yipada, kí ẹ sì máa lọ sinu aṣálẹ̀, ní apá ọ̀nà Òkun Pupa.