I. Kor 16:1-24
I. Kor 16:1-24 Bibeli Mimọ (YBCV)
NJẸ niti idawo fun awọn enia mimọ́, bi mo ti fi aṣẹ fun awọn ijọ Galatia, bẹ̃ gẹgẹ ni ki ẹ ṣe. Li ọjọ ikini ọ̀sẹ, ki olukuluku nyin fi sinu iṣura lọdọ ara rẹ̀ li apakan, gẹgẹ bi Ọlọrun ti ṣe rere fun u, ki o máṣe si ikojọ nigbati mo ba de. Ati nigbati mo ba de, ẹnikẹni ti ẹ ba fi iwe nyin yàn, awọn li emi ó rán lati mu ẹ̀bun nyin gòke lọ si Jerusalemu. Bi o ba si yẹ ki emi ki o lọ pẹlu, nwọn ó si ba mi lọ. Ṣugbọn emi o tọ̀ nyin wá, nigbati emi ba ti kọja lọ larin Makedonia: nitori emi ó kọja larin Makedonia. Boya emi ó si duro, ani, emi a si lo akoko otutu pẹlu nyin, ki ẹnyin ki o le sìn mi li ọ̀na àjo mi, nibikibi ti mo ba nlọ. Nitori emi kò fẹ ri nyin li ọ̀na-ajò nisisiyi; nitori emi nreti ati duro lọdọ nyin nigba diẹ, bi Oluwa ba fẹ. Ṣugbọn emi o duro ni Efesu titi di Pẹntikọsti. Nitoripe ilẹkun nla ati aitase ṣi silẹ fun mi, ọ̀pọlọpọ si li awọn ọtá ti mbẹ. Njẹ bi Timotiu ba de, ẹ jẹ́ ki o wà lọdọ nyin laibẹ̀ru: nitori on nṣe iṣẹ Oluwa, bi emi pẹlu ti nṣe. Nitorina ki ẹnikẹni máṣe kẹgan rẹ̀. Ṣugbọn ẹ sìn i jade lọna-ajò li alafia, ki on ki o le tọ̀ mi wá: nitoriti emi nwò ọ̀na rẹ̀ pẹlu awọn arakunrin. Ṣugbọn niti Apollo arakunrin wa, mo bẹ ẹ pupọ ki o tọ̀ nyin wá pẹlu awọn arakunrin: ṣugbọn kì iṣe ifẹ rẹ̀ rara lati wá nisisiyi; ṣugbọn on o wá nigbati o ba ni akokò ti o wọ̀. Ẹ mã ṣọra, ẹ duro gangan ni igbagbọ́, ẹ ṣe bi ọkunrin, ẹ jẹ alagbara. Ẹ mã fi ifẹ ṣe gbogbo nkan nyin. Njẹ mo bẹ nyin, ará (ẹ sá mọ̀ ile Stefana, pe awọn ni akọso Akaia, ati pe, nwọn si ti fi ara wọn fun iṣẹ-iranṣẹ awọn enia mimọ́), Ki ẹnyin ki o tẹriba fun irú awọn bawọnni, ati fun olukuluku olubaṣiṣẹ pọ̀ pẹlu wa ti o si nṣe lãla. Mo yọ̀ fun wíwa Stefana ati Fortunatu ati Akaiku: nitori eyi ti o kù nipa tinyin nwọn ti fi kún u. Nitoriti nwọn tù ẹmí mi lara ati tinyin: nitorina ẹ mã gbà irú awọn ti o ri bẹ̃. Awọn ijọ ni Asia kí nyin. Akuila ati Priskilla kí nyin pupọ ninu Oluwa, pẹlu ijọ ti o wà ni ile wọn. Gbogbo awọn arakunrin kí nyin. Ẹ fi ifẹnukonu mimọ́ kí ara nyin. Ikíni ti emi Paulu, lati ọwọ́ emi tikarami wá. Bi ẹnikẹni kò ba fẹ Jesu Kristi Oluwa, ẹ jẹ ki o di Anatema. Maranata. Õre-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa ki o pẹlu nyin. Ifẹ mi wà pẹlu gbogbo nyin ninu Kristi Jesu. Amin.
I. Kor 16:1-24 Yoruba Bible (YCE)
Nípa ti ìtọrẹ tí ẹ̀ ń ṣe fún àwọn eniyan Ọlọrun, bí mo ti ṣe ètò pẹlu àwọn ìjọ Galatia, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe. Ní ọjọọjọ́ ìsinmi, kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín máa mú ọrẹ ninu ohun ìní rẹ̀, kí ó máa fi í sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun bá ti bukun un. Kí ó má ṣe jẹ́ pé nígbà tí mo bá dé ni ẹ óo ṣẹ̀ṣẹ̀ máa gba ọrẹ jọ. Nígbà tí mo bá dé, n óo kọ ìwé lé àwọn tí ẹ bá yàn lọ́wọ́, n óo rán wọn láti mú ọrẹ yín lọ sí Jerusalẹmu. Bí ó bá yẹ kí èmi náà lọ, wọn yóo bá mi lọ. Masedonia ni n óo kọ́ gbà kọjá, n óo wá wá sọ́dọ̀ yín. Bóyá n óo dúró lọ́dọ̀ yín, mo tilẹ̀ lè wà lọ́dọ̀ yín ní àkókò òtútù, kí ẹ lè sìn mí lọ sí ibi tí mo bá tún ń lọ. Nítorí pé, nígbà tí mo bá ń kọjá lọ, n kò fẹ́ kí ó jẹ́ pé mo kàn fi ojú bà yín lásán ni. Nítorí mo ní ìrètí pé n óo lè dúró lọ́dọ̀ yín fún ìgbà díẹ̀, bí Oluwa bá gbà bẹ́ẹ̀. Mo fẹ́ dúró ní Efesu níhìn-ín títí di àjọ̀dún Pẹntikọsti. Nítorí pé mo ní anfaani pupọ láti ṣiṣẹ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alátakò pọ̀. Bí Timoti bá dé, kí ẹ rí i pé ẹ fi í lára balẹ̀ láàrin yín, nítorí iṣẹ́ Oluwa tí mò ń ṣe ni òun náà ń ṣe. Kí ẹnikẹ́ni má ṣe fi àbùkù kàn án. Ẹ ṣe ètò ìrìn àjò fún un ní alaafia, kí ó lè wá sọ́dọ̀ mi, nítorí èmi ati àwọn arakunrin ń retí rẹ̀. Nípa ti arakunrin wa Apolo, mo gbà á níyànjú gidigidi pé kí ó wá sọ́dọ̀ yín pẹlu àwọn arakunrin yòókù. Ṣugbọn ó pinnu pé òun kò fẹ́ wá ní àkókò yìí. Ó ń bọ̀ nígbà tí ó bá yá. Ẹ máa ṣọ́nà. Ẹ dúró gbọningbọnin ninu igbagbọ. Ẹ ṣe bí ọkunrin. Ẹ jẹ́ alágbára. Ẹ máa ṣe gbogbo nǹkan tìfẹ́tìfẹ́. Ará, mo ní ẹ̀bẹ̀ kan láti fi siwaju yín. Ẹ mọ̀ pé ìdílé Stefana ni àwọn kinni tí ó kọ́kọ́ gbàgbọ́ ní ilẹ̀ Akaya; ati pé wọ́n ti yan ara wọn láti máa ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún àwọn eniyan Ọlọrun. Mo fẹ́ kí ẹ máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ irú wọn ati gbogbo àwọn tí wọn bá ń bá wọn ṣiṣẹ́ pọ̀, tí wọn ń ṣe làálàá níbi iṣẹ́ kan náà. Inú mi dùn nígbà tí Stefana ati Fotunatu ati Akaiku dé, nítorí dídé tí wọ́n dé dí àlàfo tí ó ṣí sílẹ̀ nítorí àìsí yín lọ́dọ̀ wa. Wọ́n mú kí ọkàn mi balẹ̀. Ati ti ẹ̀yin náà. Ẹ máa yẹ́ irú àwọn bẹ́ẹ̀ sí. Gbogbo ìjọ tí ó wà ní Esia kí yín. Akuila ati Pirisila ati ìjọ tí ó wà ní ilé wọn ki yín pupọ ninu Oluwa. Gbogbo àwọn onigbagbọ ki yín. Ẹ fi ìfẹnukonu alaafia kí ara yín. Ọwọ́ ara mi ni èmi Paulu fi kọ gbolohun ìkíni yìí. Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ràn Oluwa wa, ẹni ègún ni! Marana ta–Oluwa wa, máa bọ̀! Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu kí ó wà pẹlu yín. Mo fi ìfẹ́ kí gbogbo yín ninu Kristi Jesu.
I. Kor 16:1-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ǹjẹ́ ní ti ìdáwó fún àwọn ènìyàn mímọ́, bí mo tí wí fún àwọn ìjọ Galatia, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní kí ẹ ṣe. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, kí olúkúlùkù yín fi sínú ìṣúra lọ́dọ̀ ara rẹ̀ ni apá kan, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe rere fún ún, ki ó má ṣe si ìkójọ nígbà tí mo bá dé. Àti nígbà ti mo bá dé, àwọn ẹni tí ẹ bá yàn, àwọn ni èmi ó rán láti mú ẹ̀bùn yín gòkè lọ si Jerusalẹmu. Bí ó bá sì yẹ kí èmí lọ pẹ̀lú, wọn ó sì bá mi lọ. Ṣùgbọ́n èmi yóò tọ̀ yin wá, nígbà tí èmí bá ti kọjá láàrín Makedonia: nítorí èmi yóò kọjá láàrín Makedonia. Bóyá èmi ó sì dúró pẹ̀lú yín, tàbí kí n tilẹ̀ lo àkókò òtútù, ki ẹ̀yin lé sìn mí ni ọ̀nà àjò mí, níbikíbi tí mo bá ń lọ. Nítorí èmi kò fẹ́ kan ri yín kí èmi sì ṣe bẹ́ẹ̀ kọjá lọ; nítorí èmi ń retí àti dúró lọ́dọ̀ yín díẹ̀, bí Olúwa bá fẹ́ Ṣùgbọ́n èmi yóò dúró ni Efesu títí dí Pentikosti. Nítorí pé ìlẹ̀kùn ńlá láti ṣe iṣẹ́ gidi ṣí sílẹ̀ fún mí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn ọ̀tá tí ń bẹ. Ǹjẹ́ bí Timotiu bá dé, ẹ jẹ́ kí ó wà lọ́dọ̀ yín láìbẹ̀rù: nítorí òun ń ṣé iṣẹ́ Olúwa, bí èmi pẹ̀lú ti ń ṣe. Nítorí náà kí ẹnikẹ́ni má ṣe kẹ́gàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ sín ín jáde lọ́nà àjò ni àlàáfíà, kí òun lè tọ̀ mí wá; nítorí tí èmí ń fi ojú sí ọ̀nà fún wíwá rẹ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin. Ṣùgbọ́n ní ti Apollo arákùnrin wa, mo bẹ̀ ẹ́ púpọ̀ láti tọ̀ yín wá pẹ̀lú àwọn arákùnrin: Ṣùgbọ́n kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ rárá láti wà nísinsin yìí, ṣùgbọ́n òun yóò wá nígbà tí ààyè bá ṣí sílẹ̀ fún un. Ẹ máa ṣọ́ra, ẹ dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́, ẹ ṣe bi ọkùnrin tí ó ní ìgboyà, ẹ jẹ́ alágbára. Ẹ máa ṣe ohun gbogbo nínú ìfẹ́. Ǹjẹ́ mo bẹ̀ yín ará, ẹ ṣá mọ ilé Stefana pé, àwọn ni ẹni àkọ́kọ́ tó gba Jesu ní Akaia, àti pé, wọn sì tí fi ará wọn fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ènìyàn mímọ́. Kí ẹ̀yin tẹríba fún irú àwọn báwọ̀nyí, àti fún olúkúlùkù olùbáṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú wa tí ó sì ń ṣe làálàá. Mo láyọ̀ fún wíwá Stefana àti Fortunatu àti Akaiku: nítorí èyí tí ó kù nípá tí yín wọ́n ti fi kún un. Nítorí tí wọ́n tu ẹ̀mí mí lára àti tiyín: nítorí náà, ẹ máa gba irú àwọn ti ó rí bẹ́ẹ̀. Àwọn ìjọ ni Asia kí í yín. Akuila àti Priskilla kí í yín púpọ̀ nínú Olúwa, pẹ̀lú ìjọ tí ó wà ni ilé wọn. Gbogbo àwọn arákùnrin kí í yín. Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín. Ìkíni ti èmi Paulu, láti ọwọ́ èmi tìkára mi wá. Bí ẹnikẹ́ni kò bá ní ìfẹ́ Jesu Kristi Olúwa, jẹ́ kí ó dì ẹni ìfibú. Máa bọ Olúwa wa! Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa kí ó wà pẹ̀lú yín! Ìfẹ́ mi wá pẹ̀lú gbogbo yín nínú Kristi Jesu. Àmín.