I. Kor 16

16
Ìtọrẹ Onigbagbọ
1NJẸ niti idawo fun awọn enia mimọ́, bi mo ti fi aṣẹ fun awọn ijọ Galatia, bẹ̃ gẹgẹ ni ki ẹ ṣe.
2Li ọjọ ikini ọ̀sẹ, ki olukuluku nyin fi sinu iṣura lọdọ ara rẹ̀ li apakan, gẹgẹ bi Ọlọrun ti ṣe rere fun u, ki o máṣe si ikojọ nigbati mo ba de.
3Ati nigbati mo ba de, ẹnikẹni ti ẹ ba fi iwe nyin yàn, awọn li emi ó rán lati mu ẹ̀bun nyin gòke lọ si Jerusalemu.
4Bi o ba si yẹ ki emi ki o lọ pẹlu, nwọn ó si ba mi lọ.
Ètò Nípa Ìrìn Àjò
5Ṣugbọn emi o tọ̀ nyin wá, nigbati emi ba ti kọja lọ larin Makedonia: nitori emi ó kọja larin Makedonia.
6Boya emi ó si duro, ani, emi a si lo akoko otutu pẹlu nyin, ki ẹnyin ki o le sìn mi li ọ̀na àjo mi, nibikibi ti mo ba nlọ.
7Nitori emi kò fẹ ri nyin li ọ̀na-ajò nisisiyi; nitori emi nreti ati duro lọdọ nyin nigba diẹ, bi Oluwa ba fẹ.
8Ṣugbọn emi o duro ni Efesu titi di Pẹntikọsti.
9Nitoripe ilẹkun nla ati aitase ṣi silẹ fun mi, ọ̀pọlọpọ si li awọn ọtá ti mbẹ.
10Njẹ bi Timotiu ba de, ẹ jẹ́ ki o wà lọdọ nyin laibẹ̀ru: nitori on nṣe iṣẹ Oluwa, bi emi pẹlu ti nṣe.
11Nitorina ki ẹnikẹni máṣe kẹgan rẹ̀. Ṣugbọn ẹ sìn i jade lọna-ajò li alafia, ki on ki o le tọ̀ mi wá: nitoriti emi nwò ọ̀na rẹ̀ pẹlu awọn arakunrin.
12Ṣugbọn niti Apollo arakunrin wa, mo bẹ ẹ pupọ ki o tọ̀ nyin wá pẹlu awọn arakunrin: ṣugbọn kì iṣe ifẹ rẹ̀ rara lati wá nisisiyi; ṣugbọn on o wá nigbati o ba ni akokò ti o wọ̀.
Gbolohun Ìparí
13Ẹ mã ṣọra, ẹ duro gangan ni igbagbọ́, ẹ ṣe bi ọkunrin, ẹ jẹ alagbara.
14Ẹ mã fi ifẹ ṣe gbogbo nkan nyin.
15Njẹ mo bẹ nyin, ará (ẹ sá mọ̀ ile Stefana, pe awọn ni akọso Akaia, ati pe, nwọn si ti fi ara wọn fun iṣẹ-iranṣẹ awọn enia mimọ́),
16Ki ẹnyin ki o tẹriba fun irú awọn bawọnni, ati fun olukuluku olubaṣiṣẹ pọ̀ pẹlu wa ti o si nṣe lãla.
17Mo yọ̀ fun wíwa Stefana ati Fortunatu ati Akaiku: nitori eyi ti o kù nipa tinyin nwọn ti fi kún u.
18Nitoriti nwọn tù ẹmí mi lara ati tinyin: nitorina ẹ mã gbà irú awọn ti o ri bẹ̃.
19Awọn ijọ ni Asia kí nyin. Akuila ati Priskilla kí nyin pupọ ninu Oluwa, pẹlu ijọ ti o wà ni ile wọn.
20Gbogbo awọn arakunrin kí nyin. Ẹ fi ifẹnukonu mimọ́ kí ara nyin.
21Ikíni ti emi Paulu, lati ọwọ́ emi tikarami wá.
22Bi ẹnikẹni kò ba fẹ Jesu Kristi Oluwa, ẹ jẹ ki o di Anatema. Maranata.
23Õre-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa ki o pẹlu nyin.
24Ifẹ mi wà pẹlu gbogbo nyin ninu Kristi Jesu. Amin.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Kor 16: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa