I. Kor 15

15
Ajinde Kristi
1NJẸ, ará, emi nsọ ihinrere na di mimọ̀ fun nyin ti mo ti wãsu fun nyin, eyiti ẹnyin pẹlu ti gbà, ninu eyi ti ẹnyin si duro;
2Nipaṣe eyiti a fi ngbà nyin là pẹlu, bi ẹnyin ba di ọ̀rọ ti mo ti wãsu fun nyin mú ṣinṣin, bikoṣepe ẹnyin ba gbagbọ́ lasan.
3Nitoripe ṣiwaju ohun gbogbo mo fi eyiti emi pẹlu ti gbà le nyin lọwọ, bi Kristi ti kú nitori ẹ̀ṣẹ wa gẹgẹ bi iwe-mimọ́ ti wi;
4Ati pe a sinkú rẹ̀, ati pe o jinde ni ijọ kẹta gẹgẹ bi iwe-mimọ́ ti wi:
5Ati pe o farahan Kefa, lẹhin eyini awọn mejila:
6Lẹhin eyini o farahan awọn ará ti o jù ẹ̃dẹgbẹta lọ lẹkanna; apakan ti o pọ̀ju ninu wọn wà titi fi di isisiyi, ṣugbọn awọn diẹ ti sùn.
7Lẹhin eyini o farahan Jakọbu; lẹhinna fun gbogbo awọn Aposteli.
8Ati nikẹhin gbogbo wọn o farahàn mi pẹlu, bi ẹni ti a bí ṣiwaju akokò rẹ̀.
9Nitori emi li ẹniti o kere jùlọ ninu awọn Aposteli, emi ẹniti kò yẹ ti a ba pè li Aposteli, nitoriti mo ṣe inunibini si ijọ enia Ọlọrun.
10Ṣugbọn nipa õre-ọfẹ Ọlọrun, mo ri bi mo ti ri: õre-ọfẹ rẹ̀ ti a fifun mi kò si jẹ asan; ṣugbọn mo ṣiṣẹ lọpọlọpọ jù gbogbo wọn lọ: ṣugbọn kì iṣe emi, bikoṣe õre-ọfẹ Ọlọrun ti o wà pẹlu mi.
11Nitorina ibã ṣe emi tabi awọn ni, bẹ̃li awa wãsu, bẹ̃li ẹnyin si gbagbọ́.
Ajinde Òkú
12Njẹ bi a ba nwasu Kristi pe o ti jinde kuro ninu okú, ẽhatiṣe ti awọn miran ninu nyin fi wipe, ajinde okú kò si?
13Ṣugbọn bi ajinde okú kò si, njẹ Kristi kò jinde:
14Bi Kristi kò ba si jinde, njẹ asan ni iwãsu wa, asan si ni igbagbọ́ nyin pẹlu.
15Pẹlupẹlu a mu wa li ẹlẹri eke fun Ọlọrun; nitoriti awa jẹri Ọlọrun pe o jí Kristi dide: ẹniti on kò jí dide, bi o ba ṣe pe awọn okú kò jinde?
16Nitoripe bi a kò bá ji awọn oku dide, njẹ a kò jí Kristi dide:
17Bi a kò ba si jí Kristi dide, asan ni igbagbọ́ nyin; ẹnyin wà ninu ẹ̀ṣẹ nyin sibẹ.
18Njẹ awọn pẹlu ti o sùn ninu Kristi ṣegbé.
19Bi o ba ṣe pe ni kìki aiye yi nikan li awa ni ireti ninu Kristi, awa jasi òtoṣi jùlọ ninu gbogbo enia.
20Njẹ nisisiyi Kristi ti jinde kuro ninu okú, o si di akọbi ninu awọn ti o sùn.
21Nitori igbati o ti ṣepe nipa enia ni ikú ti wá, nipa enia li ajinde ninu okú si ti wá pẹlu.
22Nitori bi gbogbo enia ti kú ninu Adamu, bẹ̃ni a ó si sọ gbogbo enia di alãye ninu Kristi.
23Ṣugbọn olukuluku enia ni ipa tirẹ̀: Kristi akọbi; lẹhin eyini awọn ti iṣe ti Kristi ni bibọ rẹ̀.
24Nigbana ni opin yio de, nigbati o ba ti fi ijọba fun Ọlọrun ani Baba; nigbati o ba ti mu gbogbo aṣẹ ati gbogbo ọla ati agbara kuro.
25Nitori on kò le ṣaima jọba titi yio fi fi gbogbo awọn ọta sabẹ ẹsẹ rẹ̀.
26Ikú ni ọtá ikẹhin ti a ó parun.
27Nitori o ti fi ohun gbogbo sabẹ ẹsẹ rẹ̀. Ṣugbọn nigbati o wipe ohun gbogbo li a fi sabẹ rẹ̀, o daju pe, on nikanṣoṣo li o kù, ti o fi ohun gbogbo si i labẹ.
28Nigbati a ba si fi ohun gbogbo sabẹ rẹ̀ tan, nigbana li a ó fi Ọmọ tikararẹ̀ pẹlu sabẹ ẹniti o fi ohun gbogbo sabẹ rẹ̀, ki Ọlọrun ki o le jasi ohun gbogbo li ohun gbogbo.
29Njẹ kili awọn ti a baptisi nitori okú yio ha ṣe, bi o ba ṣe pe awọn okú kò jinde rara? nitori kili a ha ṣe mbaptisi wọn nitori okú?
30Nitori kili awa si ṣe mbẹ ninu ewu ni wakati gbogbo?
31Mo sọ nipa ayọ̀ ti mo ni lori nyin ninu Kristi Jesu Oluwa wa pe, emi nkú lojojumọ́.
32Ki a wi bi enia, bi mo ba ẹranko jà ni Efesu, anfãni kili o jẹ́ fun mi? bi o ba ṣe pe awọn okú kò jinde, ẹ jẹ ki a mã jẹ, ẹ jẹ ki a mã mu; ọla li awa o sá kú.
33Ki a má tàn nyin jẹ: ẹgbẹ́ buburu bà ìwa rere jẹ.
34Ẹ jí iji ododo, ki ẹ má si dẹṣẹ̀; nitori awọn ẹlomiran kò ni ìmọ Ọlọrun: mo sọ eyi ki oju ki o le ti nyin.
Ara Lẹ́yìn Ajinde
35Ṣugbọn ẹnikan yio wipe, Bawo li a o ha ji awọn okú dide? iru ara wo ni nwọn o pada si?
36Iwọ alaimoye, ohun ti iwọ fọnrugbin ki iyè bikoṣepe o ba kú:
37Ati eyiti iwọ fọnrugbin, ara ti mbọ̀ ki iwọ fọnrugbin, ṣugbọn irugbin lasan ni, ibã ṣe alikama, tabi irú miran.
38Ṣugbọn Ọlọrun fun u li ara bi o ti wù u, ati fun olukuluku irú ara tirẹ̀.
39Gbogbo ẹran-ara kì iṣe ẹran-ara kanna: ṣugbọn ọ̀tọ li ẹran-ara ti enia, ọ̀tọ li ẹran-ara ti ẹranko, ọ̀tọ ni ti ẹja, ọ̀tọ si ni ti ẹiyẹ.
40Ara ti oke ọrun mbẹ, ara ti aiye pẹlu si mbẹ: ṣugbọn ogo ti oke ọrun ọ̀tọ, ati ogo ti aiye ọ̀tọ.
41Ọtọ li ogo ti õrùn, ọ̀tọ li ogo ti oṣupa, ọ̀tọ si li ogo ti irawọ; irawọ sá yàtọ si irawọ li ogo.
42Gẹgẹ bẹ̃ si li ajinde okú. A gbìn i ni idibajẹ; a si jí i dide li aidibajẹ:
43A gbìn i li ainiyìn; a si jí i dide li ogo: a gbìn i li ailera, a si jí i dide li agbara:
44A gbìn i li ara iyara; a si jí i dide li ara ẹmí. Bi ara iyara ba mbẹ, ara ẹmí si mbẹ.
45Bẹ̃li a si kọ ọ pe, Adamu ọkunrin iṣaju, alãye ọkàn li a da a; Adamu ikẹhin ẹmí isọnidãye.
46Ṣugbọn eyi ti iṣe ẹlẹmí kọ́ tète ṣaju, bikoṣe eyi ti iṣe ara iyara; lẹhinna eyi ti iṣe ẹlẹmí.
47Ọkunrin iṣaju ti inu erupẹ̀ wá, ẹni erupẹ̀: ọkunrin ekeji Oluwa lati ọrun wá ni.
48Bi ẹni erupẹ̀ ti ri, irú bẹ̃ si ni awọn ti iṣe ti erupẹ̀: bi ẹni ti ọrun ti ri, irú bẹ si ni awọn ti iṣe ti ọrun.
49Bi awa si ti rù aworan ẹni erupẹ̀, bẹ̃li awa ó si ru aworan ẹni ti ọrun.
50Ará, njẹ eyi ni mo wipe, ara on ẹ̀jẹ kò le jogún ijọba Ọlọrun; bẹ̃ni idibajẹ kò le jogún aidibajẹ.
51Kiyesi i, ohun ijinlẹ ni mo sọ fun nyin; gbogbo wa kì yio sùn, ṣugbọn gbogbo wa li a o palarada,
52Lọgan, ni iṣẹ́ju, nigba ipè ikẹhin: nitori ipè yio dún, a o si jí awọn okú dide li aidibajẹ, a ó si pawalara dà.
53Nitoripe ara idibajẹ yi kò le ṣaigbé aidibajẹ wọ̀, ati ara kikú yi kò le ṣaigbé ara aiku wọ̀.
54Ṣugbọn nigbati ara idibajẹ yi ba ti gbe aidibajẹ wọ̀, ti ara kikú yi ba si ti gbe aikú wọ̀ bẹ̃ tan, nigbana ni ọ̀rọ ti a kọ yio ṣẹ pe, A gbé ikú mì ni iṣẹgun.
55Ikú, oró rẹ dà? Isà okú, iṣẹgun rẹ dà?
56Oró ikú li ẹ̀ṣẹ; ati agbara ẹ̀ṣẹ li ofin.
57Ṣugbọn ọpẹ́ ni fun Ọlọrun ẹniti o fi iṣẹgun fun wa nipa Oluwa wa Jesu Kristi.
58Nitorina ẹnyin ará mi olufẹ ẹ mã duro ṣinṣin, laiyẹsẹ, ki ẹ mã pọ̀ si i ni iṣẹ Oluwa nigbagbogbo, niwọn bi ẹnyin ti mọ̀ pe iṣẹ nyin kì iṣe asan ninu Oluwa.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Kor 15: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa