1
I. Kor 15:58
Bibeli Mimọ
Nitorina ẹnyin ará mi olufẹ ẹ mã duro ṣinṣin, laiyẹsẹ, ki ẹ mã pọ̀ si i ni iṣẹ Oluwa nigbagbogbo, niwọn bi ẹnyin ti mọ̀ pe iṣẹ nyin kì iṣe asan ninu Oluwa.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí I. Kor 15:58
2
I. Kor 15:57
Ṣugbọn ọpẹ́ ni fun Ọlọrun ẹniti o fi iṣẹgun fun wa nipa Oluwa wa Jesu Kristi.
Ṣàwárí I. Kor 15:57
3
I. Kor 15:33
Ki a má tàn nyin jẹ: ẹgbẹ́ buburu bà ìwa rere jẹ.
Ṣàwárí I. Kor 15:33
4
I. Kor 15:10
Ṣugbọn nipa õre-ọfẹ Ọlọrun, mo ri bi mo ti ri: õre-ọfẹ rẹ̀ ti a fifun mi kò si jẹ asan; ṣugbọn mo ṣiṣẹ lọpọlọpọ jù gbogbo wọn lọ: ṣugbọn kì iṣe emi, bikoṣe õre-ọfẹ Ọlọrun ti o wà pẹlu mi.
Ṣàwárí I. Kor 15:10
5
I. Kor 15:55-56
Ikú, oró rẹ dà? Isà okú, iṣẹgun rẹ dà? Oró ikú li ẹ̀ṣẹ; ati agbara ẹ̀ṣẹ li ofin.
Ṣàwárí I. Kor 15:55-56
6
I. Kor 15:51-52
Kiyesi i, ohun ijinlẹ ni mo sọ fun nyin; gbogbo wa kì yio sùn, ṣugbọn gbogbo wa li a o palarada, Lọgan, ni iṣẹ́ju, nigba ipè ikẹhin: nitori ipè yio dún, a o si jí awọn okú dide li aidibajẹ, a ó si pawalara dà.
Ṣàwárí I. Kor 15:51-52
7
I. Kor 15:21-22
Nitori igbati o ti ṣepe nipa enia ni ikú ti wá, nipa enia li ajinde ninu okú si ti wá pẹlu. Nitori bi gbogbo enia ti kú ninu Adamu, bẹ̃ni a ó si sọ gbogbo enia di alãye ninu Kristi.
Ṣàwárí I. Kor 15:21-22
8
I. Kor 15:53
Nitoripe ara idibajẹ yi kò le ṣaigbé aidibajẹ wọ̀, ati ara kikú yi kò le ṣaigbé ara aiku wọ̀.
Ṣàwárí I. Kor 15:53
9
I. Kor 15:25-26
Nitori on kò le ṣaima jọba titi yio fi fi gbogbo awọn ọta sabẹ ẹsẹ rẹ̀. Ikú ni ọtá ikẹhin ti a ó parun.
Ṣàwárí I. Kor 15:25-26
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò