II. Kor Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Paulu kọ ìwé rẹ̀ keji sí àwọn ará Kọrinti ní àkókò tí ó ní ọpọlọpọ ìṣòro pẹlu ìjọ Kọrinti. Ó hàn gbangba ninu ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn kan ninu ìjọ yìí ti takò ó. Ṣugbọn ó tún hàn bákan náà pé Paulu fẹ́ tọkàntọkàn pé kí àìdọ́gba náà tètè parí, ó sì tún ń fihàn ninu ìwé yìí bí ayọ̀ rẹ̀ yóo ti pọ̀ tó nígbà tí gbogbo rúdurùdu náà bá parí.
Ninu apá kinni ìwé yìí, Paulu sọ̀rọ̀ lórí ipò rẹ̀ sí ìjọ tí ó wà ní Kọrinti. Ó ṣe àlàyé ìdí abájọ tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi le sí àwọn kan tí wọ́n fi àbùkù kàn án, tí wọ́n sì takò ó. Ó tún ṣe àlàyé pé ó dùn mọ́ òun pupọ pé líle tí ọ̀rọ̀ òun le sí wọn ni ó ṣe okùnfà ìrònúpìwàdà ati ìrẹ́pọ̀ wọn. Lẹ́yìn náà ó rọ ìjọ náà kí wọ́n ṣe ìtọrẹ àánú tí ó jọjú láti ran àwọn onigbagbọ tí wọ́n ṣe aláìní ní Judia lọ́wọ́. Ninu àwọn orí bíi mélòó kan tí ó wà ní ìparí ìwé náà, Paulu júwe bí òun ṣe jẹ́ aposteli fún àwọn kan tí wọ́n ti fi ara wọn jẹ aposteli tí wọ́n sọ pé, “Aposteli èké ni Paulu.”
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1:1-11
Paulu ati Ìjọ Kọrinti 1:12—7:16
Ìtọrẹ àánú fún àwọn onigbagbọ ní Judia 8:1—9:15
Ìdí abájọ bí Paulu ṣe jẹ́ Aposteli tí ó sì ṣe ní àṣẹ 10:1—13:10
Ọ̀rọ̀ ìparí 13:11-13

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

II. Kor Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀