NJẸ niti idawo fun awọn enia mimọ́, bi mo ti fi aṣẹ fun awọn ijọ Galatia, bẹ̃ gẹgẹ ni ki ẹ ṣe.
Li ọjọ ikini ọ̀sẹ, ki olukuluku nyin fi sinu iṣura lọdọ ara rẹ̀ li apakan, gẹgẹ bi Ọlọrun ti ṣe rere fun u, ki o máṣe si ikojọ nigbati mo ba de.
Ati nigbati mo ba de, ẹnikẹni ti ẹ ba fi iwe nyin yàn, awọn li emi ó rán lati mu ẹ̀bun nyin gòke lọ si Jerusalemu.
Bi o ba si yẹ ki emi ki o lọ pẹlu, nwọn ó si ba mi lọ.
Ṣugbọn emi o tọ̀ nyin wá, nigbati emi ba ti kọja lọ larin Makedonia: nitori emi ó kọja larin Makedonia.
Boya emi ó si duro, ani, emi a si lo akoko otutu pẹlu nyin, ki ẹnyin ki o le sìn mi li ọ̀na àjo mi, nibikibi ti mo ba nlọ.
Nitori emi kò fẹ ri nyin li ọ̀na-ajò nisisiyi; nitori emi nreti ati duro lọdọ nyin nigba diẹ, bi Oluwa ba fẹ.
Ṣugbọn emi o duro ni Efesu titi di Pẹntikọsti.
Nitoripe ilẹkun nla ati aitase ṣi silẹ fun mi, ọ̀pọlọpọ si li awọn ọtá ti mbẹ.
Njẹ bi Timotiu ba de, ẹ jẹ́ ki o wà lọdọ nyin laibẹ̀ru: nitori on nṣe iṣẹ Oluwa, bi emi pẹlu ti nṣe.
Nitorina ki ẹnikẹni máṣe kẹgan rẹ̀. Ṣugbọn ẹ sìn i jade lọna-ajò li alafia, ki on ki o le tọ̀ mi wá: nitoriti emi nwò ọ̀na rẹ̀ pẹlu awọn arakunrin.
Ṣugbọn niti Apollo arakunrin wa, mo bẹ ẹ pupọ ki o tọ̀ nyin wá pẹlu awọn arakunrin: ṣugbọn kì iṣe ifẹ rẹ̀ rara lati wá nisisiyi; ṣugbọn on o wá nigbati o ba ni akokò ti o wọ̀.
Ẹ mã ṣọra, ẹ duro gangan ni igbagbọ́, ẹ ṣe bi ọkunrin, ẹ jẹ alagbara.
Ẹ mã fi ifẹ ṣe gbogbo nkan nyin.
Njẹ mo bẹ nyin, ará (ẹ sá mọ̀ ile Stefana, pe awọn ni akọso Akaia, ati pe, nwọn si ti fi ara wọn fun iṣẹ-iranṣẹ awọn enia mimọ́),
Ki ẹnyin ki o tẹriba fun irú awọn bawọnni, ati fun olukuluku olubaṣiṣẹ pọ̀ pẹlu wa ti o si nṣe lãla.
Mo yọ̀ fun wíwa Stefana ati Fortunatu ati Akaiku: nitori eyi ti o kù nipa tinyin nwọn ti fi kún u.
Nitoriti nwọn tù ẹmí mi lara ati tinyin: nitorina ẹ mã gbà irú awọn ti o ri bẹ̃.
Awọn ijọ ni Asia kí nyin. Akuila ati Priskilla kí nyin pupọ ninu Oluwa, pẹlu ijọ ti o wà ni ile wọn.
Gbogbo awọn arakunrin kí nyin. Ẹ fi ifẹnukonu mimọ́ kí ara nyin.
Ikíni ti emi Paulu, lati ọwọ́ emi tikarami wá.
Bi ẹnikẹni kò ba fẹ Jesu Kristi Oluwa, ẹ jẹ ki o di Anatema. Maranata.
Õre-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa ki o pẹlu nyin.
Ifẹ mi wà pẹlu gbogbo nyin ninu Kristi Jesu. Amin.