KỌRINTI KINNI 16

16
Ìtọrẹ Onigbagbọ
1Nípa ti ìtọrẹ tí ẹ̀ ń ṣe fún àwọn eniyan Ọlọrun, bí mo ti ṣe ètò pẹlu àwọn ìjọ Galatia, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe.#Rom 15:25-26 2Ní ọjọọjọ́ ìsinmi, kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín máa mú ọrẹ ninu ohun ìní rẹ̀, kí ó máa fi í sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun bá ti bukun un. Kí ó má ṣe jẹ́ pé nígbà tí mo bá dé ni ẹ óo ṣẹ̀ṣẹ̀ máa gba ọrẹ jọ. 3Nígbà tí mo bá dé, n óo kọ ìwé lé àwọn tí ẹ bá yàn lọ́wọ́, n óo rán wọn láti mú ọrẹ yín lọ sí Jerusalẹmu. 4Bí ó bá yẹ kí èmi náà lọ, wọn yóo bá mi lọ.
Ètò Nípa Ìrìn Àjò
5Masedonia ni n óo kọ́ gbà kọjá, n óo wá wá sọ́dọ̀ yín.#A. Apo 19:21 6Bóyá n óo dúró lọ́dọ̀ yín, mo tilẹ̀ lè wà lọ́dọ̀ yín ní àkókò òtútù, kí ẹ lè sìn mí lọ sí ibi tí mo bá tún ń lọ. 7Nítorí pé, nígbà tí mo bá ń kọjá lọ, n kò fẹ́ kí ó jẹ́ pé mo kàn fi ojú bà yín lásán ni. Nítorí mo ní ìrètí pé n óo lè dúró lọ́dọ̀ yín fún ìgbà díẹ̀, bí Oluwa bá gbà bẹ́ẹ̀.
8Mo fẹ́ dúró ní Efesu níhìn-ín títí di àjọ̀dún Pẹntikọsti.#Lef 23:15-21; Diut 16:9-11 9Nítorí pé mo ní anfaani pupọ láti ṣiṣẹ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alátakò pọ̀.#A. Apo 19:8-10
10Bí Timoti bá dé, kí ẹ rí i pé ẹ fi í lára balẹ̀ láàrin yín, nítorí iṣẹ́ Oluwa tí mò ń ṣe ni òun náà ń ṣe.#1 Kọr 4:17 11Kí ẹnikẹ́ni má ṣe fi àbùkù kàn án. Ẹ ṣe ètò ìrìn àjò fún un ní alaafia, kí ó lè wá sọ́dọ̀ mi, nítorí èmi ati àwọn arakunrin ń retí rẹ̀.
12Nípa ti arakunrin wa Apolo, mo gbà á níyànjú gidigidi pé kí ó wá sọ́dọ̀ yín pẹlu àwọn arakunrin yòókù. Ṣugbọn ó pinnu pé òun kò fẹ́ wá ní àkókò yìí. Ó ń bọ̀ nígbà tí ó bá yá.
Gbolohun Ìparí
13Ẹ máa ṣọ́nà. Ẹ dúró gbọningbọnin ninu igbagbọ. Ẹ ṣe bí ọkunrin. Ẹ jẹ́ alágbára. 14Ẹ máa ṣe gbogbo nǹkan tìfẹ́tìfẹ́.
15Ará, mo ní ẹ̀bẹ̀ kan láti fi siwaju yín. Ẹ mọ̀ pé ìdílé Stefana ni àwọn kinni tí ó kọ́kọ́ gbàgbọ́ ní ilẹ̀ Akaya; ati pé wọ́n ti yan ara wọn láti máa ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún àwọn eniyan Ọlọrun.#1 Kọr 1:16 16Mo fẹ́ kí ẹ máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ irú wọn ati gbogbo àwọn tí wọn bá ń bá wọn ṣiṣẹ́ pọ̀, tí wọn ń ṣe làálàá níbi iṣẹ́ kan náà.
17Inú mi dùn nígbà tí Stefana ati Fotunatu ati Akaiku dé, nítorí dídé tí wọ́n dé dí àlàfo tí ó ṣí sílẹ̀ nítorí àìsí yín lọ́dọ̀ wa. 18Wọ́n mú kí ọkàn mi balẹ̀. Ati ti ẹ̀yin náà. Ẹ máa yẹ́ irú àwọn bẹ́ẹ̀ sí.
19Gbogbo ìjọ tí ó wà ní Esia kí yín. Akuila ati Pirisila ati ìjọ tí ó wà ní ilé wọn ki yín pupọ ninu Oluwa.#A. Apo 18:2 20Gbogbo àwọn onigbagbọ ki yín. Ẹ fi ìfẹnukonu alaafia kí ara yín.
21Ọwọ́ ara mi ni èmi Paulu fi kọ gbolohun ìkíni yìí.
22Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ràn Oluwa wa, ẹni ègún ni!
Marana ta–Oluwa wa, máa bọ̀!
23Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu kí ó wà pẹlu yín.
24Mo fi ìfẹ́ kí gbogbo yín ninu Kristi Jesu.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

KỌRINTI KINNI 16: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa