Òtítọ́ ni èmi ń sọ nínú Kristi, èmi kò ṣèké, ọkàn mi sì ń jẹ́ mi ní ẹ̀rí nínú Ẹ̀mí Mímọ́. Pé mo ní ìbìnújẹ́ púpọ̀, àti ìkáàánú ìgbà gbogbo ni ọkàn mi. Nítorí mo fẹ́rẹ lè gbàdúrà pé kí èmi tìkára mi kúrò lọ́dọ̀ Kristi nítorí àwọn ará mi, àwọn ìbátan mi nípa ti ara. Àwọn ẹni tí i ṣe Israẹli; tí àwọn ẹni tí ìsọdọmọ í ṣe, àti ògo, àti májẹ̀mú, àti ìfúnilófin, àti ìsìn Ọlọ́run, àti àwọn ìlérí. Tí ẹni tí àwọn Baba í ṣe, àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹni tí Kristi ti wá nípa ti ara, ẹni tí ó borí ohun gbogbo, Ọlọ́run olùbùkún láéláé. Àmín.
Ṣùgbọ́n kì í ṣe pé nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán. Kì í sá í ṣe gbogbo àwọn tí ó ti inú Israẹli wá, àwọn ni Israẹli: Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé, nítorí wọ́n jẹ́ irú-ọmọ Abrahamu, gbogbo wọn ni ọmọ: Ní ọ̀nà mìíràn, “Nínú Isaaki ni a ó ti pe irú-ọmọ rẹ̀.” Èyí nì ni pé, kì í ṣe àwọn ọmọ nípa ti ara, ni ọmọ Ọlọ́run: ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìlérí ni a kà ní irú-ọmọ. Nítorí ọ̀rọ̀ ìlérí ni èyí: “Ní ìwòyí àmọ́dún ni èmi yóò wá, Sara yóò sì ní ọmọ ọkùnrin.”
Kì í sì í ṣe kìkì èyí; Ṣùgbọ́n nígbà tí Rebeka pẹ̀lú lóyún fún ẹnìkan, fún Isaaki baba wa. Nítorí nígbà tí kò tí ì bí àwọn ọmọ náà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tí ì ṣe rere tàbí búburú—kí ìpinnu Ọlọ́run nípa ti ìyànfẹ́ kí ó lè dúró, kì í ṣe nípa ti iṣẹ́, bí kò ṣe ti ẹni tí ń peni—a ti sọ fún un pé, “Ẹ̀gbọ́n ni yóò máa sin àbúrò.” Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Jakọbu ni mo fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Esau ni mo kórìíra.”
Ǹjẹ́ àwa yóò ha ti wí? Àìṣòdodo ha wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run bí? Kí a má ri! Nítorí ó wí fún Mose pé,
“Èmi ó ṣàánú fún ẹni tí èmi yóò ṣàánú fún,
èmi yóò sì ṣe ìyọ́nú fún ẹni tí èmi yóò ṣe ìyọ́nú fún.”
Ǹjẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ti ẹni tí ó fẹ́, kì í sì í ṣe ti ẹni tí ń sáré, bí kò ṣe ti Ọlọ́run tí ń ṣàánú. Nítorí ìwé mímọ́ wí fún Farao pé, “Nítorí èyí náà ni mo ṣe gbé ọ dìde, kí èmi kí ó le fi agbára mi hàn lára rẹ, àti kí a bá à le máa ròyìn orúkọ mi ká gbogbo ayé.” Nítorí náà ni ó ṣe ń ṣàánú fún ẹni tí ó wù ú, ẹni tí ó wù ú a sì mú ní ọkàn le.
Ìwọ ó sì wí fún mi pé, “Kín ni ó ha tún bá ni wí sí? Nítorí ta ni ó ń de ìfẹ́ rẹ lọ́nà?” Bẹ́ẹ̀ kọ́, ìwọ ènìyàn, tà ni ìwọ tí ń dá Ọlọ́run lóhùn? “Ohun tí a mọ, a ha máa wí fún ẹni tí ó mọ ọ́n pé, ‘Èéṣe tí ìwọ fi mọ mi báyìí?’ ” Amọ̀kòkò kò ha ni agbára lórí amọ̀, nínú ìṣù kan náà láti ṣe apá kan nínú ohun èlò sí ọlá, àti apá kan nínú ohun èlò sí àìlọ́lá?
Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá fẹ́ fi ìbínú rẹ̀ hàn ńkọ́? Tí ó sì fẹ́ sọ agbára rẹ̀ di mí mọ̀, tí ó sì mú sùúrù púpọ̀ fún àwọn ohun èlò ìbínú tí a ṣe fún ìparun; Àti kí ó lè sọ ọ̀rọ̀ ògo rẹ̀ di mí mọ̀ lára àwọn ohun èlò àánú tí ó ti pèsè ṣáájú fún ògo, Àní àwa, tí ó ti pè, kì í ṣe nínú àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nínú àwọn Kèfèrí pẹ̀lú? Bí ó ti wí pẹ̀lú ní Hosea pé,
“Èmi ó pe àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi, ní ènìyàn mi,
àti ẹni tí kí í ṣe àyànfẹ́ ní àyànfẹ́.”
Yóò sì ṣe,
“Ní ibi ti a gbé ti sọ fún wọn pé,
‘ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’
níbẹ̀ ni a ó gbé pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run alààyè.’ ”