Rom 9:1-26

Rom 9:1-26 YBCV

OTITỌ li emi nsọ ninu Kristi, emi kò ṣeke, ọkàn mi si njẹ mi li ẹrí ninu Ẹmí Mimọ́, Pe mo ni ibinujẹ pupọ, ati ikãnu igbagbogbo li ọkàn mi. Nitori mo fẹrẹ le gbadura pe ki a ké emi tikarami kuro lọdọ Kristi, nitori awọn ará mi, awọn ibatan mi nipa ti ara: Awọn ẹniti iṣe Israeli; ti awọn ẹniti isọdọmọ iṣe, ati ogo, ati majẹmu, ati ifunnilofin, ati ìsin Ọlọrun, ati awọn ileri; Ti ẹniti awọn baba iṣe, ati lati ọdọ awọn ẹniti Kristi ti wá nipa ti ara, ẹniti o bori ohun gbogbo, Ọlọrun olubukún lailai. Amin. Ṣugbọn kì iṣe pe nitori ọrọ Ọlọrun di asan. Kì sá iṣe gbogbo awọn ti o ti inu Israeli wá, awọn ni Israeli: Bẹ̃ni kì iṣe pe, nitori nwọn jẹ irú-ọmọ Abrahamu, gbogbo wọn li ọmọ: ṣugbọn, ninu Isaaki li a ó ti pè irú-ọmọ rẹ. Eyini ni pe, ki iṣe awọn ọmọ nipa ti ara, ni ọmọ Ọlọrun: ṣugbọn awọn ọmọ ileri li a kà ni irú-ọmọ. Nitori ọ̀rọ ileri li eyi, Niwoyi amọdun li emi ó wá; Sara yio si ni ọmọkunrin. Kì si iṣe kìki eyi; ṣugbọn nigbati Rebekka pẹlu lóyun fun ẹnikan, fun Isaaki baba wa; Nitori nigbati a kò ti ibí awọn ọmọ na, bẹ̃ni nwọn kò ti iṣe rere tabi buburu, (ki ipinnu Ọlọrun nipa ti iyanfẹ ki o le duro, kì iṣe nipa ti iṣẹ, bikoṣe ti ẹni ti npè ni;) A ti sọ fun u pe, Ẹgbọn ni yio ma sìn aburo, Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Jakọbu ni mo fẹran, ṣugbọn Esau ni mo korira. Njẹ awa o ha ti wi? Aiṣododo ha wà lọdọ Ọlọrun bi? Ki a má ri. Nitori o wi fun Mose pe, Emi ó ṣãnu fun ẹniti emi ó ṣãnu fun, emi o si ṣe iyọ́nu fun ẹniti emi o ṣe iyọ́nu fun. Njẹ bẹ̃ni kì iṣe ti ẹniti o fẹ, kì si iṣe ti ẹniti nsáre, bikoṣe ti Ọlọrun ti nṣãnu. Nitori iwe-mimọ́ wi fun Farao pe, Nitori eyiyi na ni mo ṣe gbé ọ dide, ki emi ki o le fi agbara mi hàn lara rẹ, ki a si le mã ròhin orukọ mi ká gbogbo aiye. Nitorina li o ṣe nṣãnu fun ẹniti o wù u, ẹniti o wù u a si mu u li ọkàn le. Iwọ o si wi fun mi pe, Kili ó ha tun ba ni wi si? Nitori tali o ndè ifẹ rẹ̀ lọ̀na? Bẹ̃kọ, iwọ enia, tani iwọ ti nda Ọlọrun lohùn? Ohun ti a mọ a ha mã wi fun ẹniti ti o mọ ọ pé, Ẽṣe ti iwọ fi mọ mi bayi? Amọ̀koko kò ha li agbara lori amọ̀, ninu ìṣu kanna lati ṣe apakan li ohun elo si ọlá, ati apakan li ohun elo si ailọlá? Njẹ bi Ọlọrun ba fẹ fi ibinu rẹ̀ hàn nkọ, ti o si fẹ sọ agbara rẹ̀ di mimọ̀, ti o si mu suru pupọ fun awọn ohun elo ibinu ti a ṣe fun iparun; Ati ki o le sọ ọrọ̀ ogo rẹ̀ di mimọ̀ lara awọn ohun elo ãnu ti o ti pèse ṣaju fun ogo, Ani awa, ti o ti pè, kì iṣe ninu awọn Ju nikan, ṣugbọn ninu awọn Keferi pẹlu? Bi o ti wi pẹlu ni Hosea pe, Emi ó pè awọn ti kì iṣe enia mi, li enia mi, ati ẹniti ki iṣe ayanfẹ li ayanfẹ. Yio si ṣe, ni ibi ti a gbé ti sọ fun wọn pe, Ẹnyin kì iṣe enia mi, nibẹ̀ li a o gbé pè wọn li ọmọ Ọlọrun alãye.