Rom 9:1-26

Rom 9:1-26 Bibeli Mimọ (YBCV)

OTITỌ li emi nsọ ninu Kristi, emi kò ṣeke, ọkàn mi si njẹ mi li ẹrí ninu Ẹmí Mimọ́, Pe mo ni ibinujẹ pupọ, ati ikãnu igbagbogbo li ọkàn mi. Nitori mo fẹrẹ le gbadura pe ki a ké emi tikarami kuro lọdọ Kristi, nitori awọn ará mi, awọn ibatan mi nipa ti ara: Awọn ẹniti iṣe Israeli; ti awọn ẹniti isọdọmọ iṣe, ati ogo, ati majẹmu, ati ifunnilofin, ati ìsin Ọlọrun, ati awọn ileri; Ti ẹniti awọn baba iṣe, ati lati ọdọ awọn ẹniti Kristi ti wá nipa ti ara, ẹniti o bori ohun gbogbo, Ọlọrun olubukún lailai. Amin. Ṣugbọn kì iṣe pe nitori ọrọ Ọlọrun di asan. Kì sá iṣe gbogbo awọn ti o ti inu Israeli wá, awọn ni Israeli: Bẹ̃ni kì iṣe pe, nitori nwọn jẹ irú-ọmọ Abrahamu, gbogbo wọn li ọmọ: ṣugbọn, ninu Isaaki li a ó ti pè irú-ọmọ rẹ. Eyini ni pe, ki iṣe awọn ọmọ nipa ti ara, ni ọmọ Ọlọrun: ṣugbọn awọn ọmọ ileri li a kà ni irú-ọmọ. Nitori ọ̀rọ ileri li eyi, Niwoyi amọdun li emi ó wá; Sara yio si ni ọmọkunrin. Kì si iṣe kìki eyi; ṣugbọn nigbati Rebekka pẹlu lóyun fun ẹnikan, fun Isaaki baba wa; Nitori nigbati a kò ti ibí awọn ọmọ na, bẹ̃ni nwọn kò ti iṣe rere tabi buburu, (ki ipinnu Ọlọrun nipa ti iyanfẹ ki o le duro, kì iṣe nipa ti iṣẹ, bikoṣe ti ẹni ti npè ni;) A ti sọ fun u pe, Ẹgbọn ni yio ma sìn aburo, Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Jakọbu ni mo fẹran, ṣugbọn Esau ni mo korira. Njẹ awa o ha ti wi? Aiṣododo ha wà lọdọ Ọlọrun bi? Ki a má ri. Nitori o wi fun Mose pe, Emi ó ṣãnu fun ẹniti emi ó ṣãnu fun, emi o si ṣe iyọ́nu fun ẹniti emi o ṣe iyọ́nu fun. Njẹ bẹ̃ni kì iṣe ti ẹniti o fẹ, kì si iṣe ti ẹniti nsáre, bikoṣe ti Ọlọrun ti nṣãnu. Nitori iwe-mimọ́ wi fun Farao pe, Nitori eyiyi na ni mo ṣe gbé ọ dide, ki emi ki o le fi agbara mi hàn lara rẹ, ki a si le mã ròhin orukọ mi ká gbogbo aiye. Nitorina li o ṣe nṣãnu fun ẹniti o wù u, ẹniti o wù u a si mu u li ọkàn le. Iwọ o si wi fun mi pe, Kili ó ha tun ba ni wi si? Nitori tali o ndè ifẹ rẹ̀ lọ̀na? Bẹ̃kọ, iwọ enia, tani iwọ ti nda Ọlọrun lohùn? Ohun ti a mọ a ha mã wi fun ẹniti ti o mọ ọ pé, Ẽṣe ti iwọ fi mọ mi bayi? Amọ̀koko kò ha li agbara lori amọ̀, ninu ìṣu kanna lati ṣe apakan li ohun elo si ọlá, ati apakan li ohun elo si ailọlá? Njẹ bi Ọlọrun ba fẹ fi ibinu rẹ̀ hàn nkọ, ti o si fẹ sọ agbara rẹ̀ di mimọ̀, ti o si mu suru pupọ fun awọn ohun elo ibinu ti a ṣe fun iparun; Ati ki o le sọ ọrọ̀ ogo rẹ̀ di mimọ̀ lara awọn ohun elo ãnu ti o ti pèse ṣaju fun ogo, Ani awa, ti o ti pè, kì iṣe ninu awọn Ju nikan, ṣugbọn ninu awọn Keferi pẹlu? Bi o ti wi pẹlu ni Hosea pe, Emi ó pè awọn ti kì iṣe enia mi, li enia mi, ati ẹniti ki iṣe ayanfẹ li ayanfẹ. Yio si ṣe, ni ibi ti a gbé ti sọ fun wọn pe, Ẹnyin kì iṣe enia mi, nibẹ̀ li a o gbé pè wọn li ọmọ Ọlọrun alãye.

Rom 9:1-26 Yoruba Bible (YCE)

Òtítọ́ ni ohun tí mò ń sọ yìí; n kò purọ́, nítorí Kristi ni ó ni mí. Ọkàn mi tí Ẹ̀mí ń darí sì jẹ́ mi lẹ́rìí pẹlu, pé, ohun ìbànújẹ́ ńlá ati ẹ̀dùn ọkàn ni ọ̀ràn àwọn eniyan mi jẹ́ fún mi nígbà gbogbo. Mo fẹ́rẹ̀ lè gbadura pé kí á sọ èmi fúnra mi di ẹni ègún, kí á yà mí nípa kúrò lọ́dọ̀ Kristi nítorí ti àwọn ará mi, àwọn tí a jọ jẹ́ ẹ̀yà kan náà. Ọmọ Israẹli ni wọ́n. Àwọn ni Ọlọrun yàn bí ọmọ rẹ̀. Àwọn ni ó fi ògo rẹ̀ hàn fún. Àwọn náà ni ó bá dá majẹmu, tí ó fún ní Òfin rẹ̀, tí ó sì kọ́ lọ́nà ẹ̀sìn rẹ̀. Àwọn ni ó ṣe ìlérí fún. Àwọn ni irú-ọmọ àwọn baba-ńlá ayé àtijọ́. Láàrin wọn ni Mesaya sì ti wá sáyé gẹ́gẹ́ bí eniyan. Ìyìn ni fún Ọlọrun, ẹni tíí ṣe olùdarí ohun gbogbo, lae ati laelae. Amin. Sibẹ, kì í ṣe pé ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti kùnà patapata. Nítorí kì í ṣe gbogbo àwọn tí a bí sinu ìdílé Israẹli ni ọmọ Israẹli tòótọ́. Kì í ṣe gbogbo àwọn tí ó jẹ́ ìran Abrahamu ni ọmọ rẹ̀ tòótọ́, nítorí bí Ìwé Mímọ́ ti wí, Ọlọrun sọ fún Abrahamu pé, “Àwọn ọmọ Isaaki nìkan ni a óo kà sí ìran fún ọ.” Èyí ni pé, kì í ṣe àwọn ọmọ tí a bí nípa ti ara lásán ni ọmọ Ọlọrun. Àwọn ọmọ tí a bí nípa ìlérí Ọlọrun ni a kà sí ìran Abrahamu. Nítorí báyìí ni ọ̀rọ̀ ìlérí náà: “Nígbà tí mo bá pada wá ní ìwòyí àmọ́dún, Sara yóo ti bí ọmọkunrin kan.” Èyí nìkan kọ́. Rebeka bímọ meji fún ẹnìkan ṣoṣo, òun náà ni baba wa Isaaki. Ṣugbọn kí á tó bí àwọn ọmọ náà, àní sẹ́, kí wọ́n tó dá ohunkohun ṣe, yálà rere ni tabi burúkú, ni Ọlọrun ti sọ fún Rebeka pé, “Èyí ẹ̀gbọ́n ni yóo máa ṣe iranṣẹ àbúrò rẹ̀.” Báyìí ni Ọlọrun ti ń ṣe ìpinnu rẹ̀ láti ayébáyé, nígbà tí ó bá yan àwọn kan. Ó wá hàn kedere pé Ọlọrun kì í wo iṣẹ́ ọwọ́ eniyan kí ó tó yàn wọ́n; àwọn tí ó bá pinnu tẹ́lẹ̀ láti yàn ní í pè. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Jakọbu ni mo yàn, Esau ni mo kọ̀.” Kí ni kí á wá wí sí èyí? Kí á wí pé Ọlọrun ń ṣe àìdára ni bí? Rárá o! Nítorí ó sọ fún Mose pé, “Ẹni tí mo bá fẹ́ ṣàánú ni n óo ṣàánú; ẹni tí mo bá sì fẹ́ yọ́nú sí ni n óo yọ́nú sí.” Nítorí náà, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí eniyan ti fẹ́ tabi bí ó ti gbìyànjú tó ni Ọlọrun fi ń yàn án, bí ó bá ti wu Ọlọrun ninu àánú rẹ̀ ni. Nítorí Ọlọrun sọ ninu Ìwé Mímọ́ nípa Farao pé, “Ìdí tí mo fi fi ọ́ jọba ni pé, mo fẹ́ fi ọ́ ṣe àpẹẹrẹ bí agbára mi ti tó, ati pé kì ìròyìn orúkọ mi lè tàn ká gbogbo ayé.” Nítorí náà, ẹni tí ó bá wu Ọlọrun láti ṣàánú, a ṣàánú rẹ̀, ẹni tí ó bá sì wù ú láti dí lọ́kàn, a dí i lọ́kàn. Wàyí, ẹnìkan lè sọ fún mi pé, “Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló dé tí Ọlọrun fi ń bá eniyan wí? Ta ni ó tó takò ó pé kí ó má ṣe ohun tí ó bá wù ú?” Ṣugbọn ta ni ọ́, ìwọ ọmọ-eniyan, tí o fi ń gbó Ọlọrun lẹ́nu? Ǹjẹ́ ìkòkò lè wí fún ẹni tí ó ń mọ ọ́n pé, “Kí ló dé tí o fi ṣe mí báyìí?” Àbí amọ̀kòkò kò ní ẹ̀tọ́ láti ṣe amọ̀ rẹ̀ bí ó ti wù ú bí? Bí ó bá fẹ́, ó lè fi amọ̀ rẹ̀ mọ ìkòkò tí ó wà fún èèlò ọ̀ṣọ́. Bí ó bá sì tún fẹ́, ó lè mú lára amọ̀ kan náà kí ó fi mọ ìkòkò mìíràn fún èèlò lásán. Bẹ́ẹ̀ náà ni ohun tí Ọlọrun ṣe rí. Ó wù ú láti fi ibinu ati agbára rẹ̀ hàn. Ó wá fi ọ̀pọ̀ sùúrù fara da àwọn tí ó yẹ kí ó fi ibinu parun. Báyìí náà ni ó fi ògo ńlá rẹ̀ hàn pẹlu fún àwọn tí ó ṣàánú fún, àní fún àwa tí ó ti pèsè ọlá sílẹ̀ fún. Àwa náà ni ó pè láti ààrin àwọn Juu ati láti ààrin àwọn tí kìí ṣe Juu pẹlu; bí ó ti sọ ninu Ìwé Hosia pé, “Èmi yóo pe àwọn tí kì í ṣe eniyan mi ní ‘Eniyan mi.’ N óo sì pe àwọn orílẹ̀-èdè tí n kò náání ní ‘Àyànfẹ́ mi.’ Ní ibìkan náà tí a ti sọ fún wọn rí pé, ‘Ẹ kì í ṣe eniyan mi mọ́’ ni a óo ti pè wọ́n ní ọmọ Ọlọrun alààyè.”

Rom 9:1-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Òtítọ́ ni èmi ń sọ nínú Kristi, èmi kò ṣèké, ọkàn mi sì ń jẹ́ mi ní ẹ̀rí nínú Ẹ̀mí Mímọ́. Pé mo ní ìbìnújẹ́ púpọ̀, àti ìkáàánú ìgbà gbogbo ni ọkàn mi. Nítorí mo fẹ́rẹ lè gbàdúrà pé kí èmi tìkára mi kúrò lọ́dọ̀ Kristi nítorí àwọn ará mi, àwọn ìbátan mi nípa ti ara. Àwọn ẹni tí i ṣe Israẹli; tí àwọn ẹni tí ìsọdọmọ í ṣe, àti ògo, àti májẹ̀mú, àti ìfúnilófin, àti ìsìn Ọlọ́run, àti àwọn ìlérí. Tí ẹni tí àwọn Baba í ṣe, àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹni tí Kristi ti wá nípa ti ara, ẹni tí ó borí ohun gbogbo, Ọlọ́run olùbùkún láéláé. Àmín. Ṣùgbọ́n kì í ṣe pé nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán. Kì í sá í ṣe gbogbo àwọn tí ó ti inú Israẹli wá, àwọn ni Israẹli: Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé, nítorí wọ́n jẹ́ irú-ọmọ Abrahamu, gbogbo wọn ni ọmọ: Ní ọ̀nà mìíràn, “Nínú Isaaki ni a ó ti pe irú-ọmọ rẹ̀.” Èyí nì ni pé, kì í ṣe àwọn ọmọ nípa ti ara, ni ọmọ Ọlọ́run: ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìlérí ni a kà ní irú-ọmọ. Nítorí ọ̀rọ̀ ìlérí ni èyí: “Ní ìwòyí àmọ́dún ni èmi yóò wá, Sara yóò sì ní ọmọ ọkùnrin.” Kì í sì í ṣe kìkì èyí; Ṣùgbọ́n nígbà tí Rebeka pẹ̀lú lóyún fún ẹnìkan, fún Isaaki baba wa. Nítorí nígbà tí kò tí ì bí àwọn ọmọ náà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tí ì ṣe rere tàbí búburú—kí ìpinnu Ọlọ́run nípa ti ìyànfẹ́ kí ó lè dúró, kì í ṣe nípa ti iṣẹ́, bí kò ṣe ti ẹni tí ń peni—a ti sọ fún un pé, “Ẹ̀gbọ́n ni yóò máa sin àbúrò.” Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Jakọbu ni mo fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Esau ni mo kórìíra.” Ǹjẹ́ àwa yóò ha ti wí? Àìṣòdodo ha wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run bí? Kí a má ri! Nítorí ó wí fún Mose pé, “Èmi ó ṣàánú fún ẹni tí èmi yóò ṣàánú fún, èmi yóò sì ṣe ìyọ́nú fún ẹni tí èmi yóò ṣe ìyọ́nú fún.” Ǹjẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ti ẹni tí ó fẹ́, kì í sì í ṣe ti ẹni tí ń sáré, bí kò ṣe ti Ọlọ́run tí ń ṣàánú. Nítorí ìwé mímọ́ wí fún Farao pé, “Nítorí èyí náà ni mo ṣe gbé ọ dìde, kí èmi kí ó le fi agbára mi hàn lára rẹ, àti kí a bá à le máa ròyìn orúkọ mi ká gbogbo ayé.” Nítorí náà ni ó ṣe ń ṣàánú fún ẹni tí ó wù ú, ẹni tí ó wù ú a sì mú ní ọkàn le. Ìwọ ó sì wí fún mi pé, “Kín ni ó ha tún bá ni wí sí? Nítorí ta ni ó ń de ìfẹ́ rẹ lọ́nà?” Bẹ́ẹ̀ kọ́, ìwọ ènìyàn, tà ni ìwọ tí ń dá Ọlọ́run lóhùn? “Ohun tí a mọ, a ha máa wí fún ẹni tí ó mọ ọ́n pé, ‘Èéṣe tí ìwọ fi mọ mi báyìí?’ ” Amọ̀kòkò kò ha ni agbára lórí amọ̀, nínú ìṣù kan náà láti ṣe apá kan nínú ohun èlò sí ọlá, àti apá kan nínú ohun èlò sí àìlọ́lá? Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá fẹ́ fi ìbínú rẹ̀ hàn ńkọ́? Tí ó sì fẹ́ sọ agbára rẹ̀ di mí mọ̀, tí ó sì mú sùúrù púpọ̀ fún àwọn ohun èlò ìbínú tí a ṣe fún ìparun; Àti kí ó lè sọ ọ̀rọ̀ ògo rẹ̀ di mí mọ̀ lára àwọn ohun èlò àánú tí ó ti pèsè ṣáájú fún ògo, Àní àwa, tí ó ti pè, kì í ṣe nínú àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nínú àwọn Kèfèrí pẹ̀lú? Bí ó ti wí pẹ̀lú ní Hosea pé, “Èmi ó pe àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi, ní ènìyàn mi, àti ẹni tí kí í ṣe àyànfẹ́ ní àyànfẹ́.” Yóò sì ṣe, “Ní ibi ti a gbé ti sọ fún wọn pé, ‘ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’ níbẹ̀ ni a ó gbé pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run alààyè.’ ”