Saamu 84:5-8

Saamu 84:5-8 YCB

Ìbùkún ni fún àwọn tí agbára wọn wà nínú rẹ àwọn tí wọ́n gbé ọkàn lé bíbẹ ibi mímọ́ wò. Àwọn tí ń la Àfonífojì omijé lọ wọn sọ ọ́ di kànga àkọ́rọ̀ òjò sì fi ìbùkún bò ó; Wọ́n ń lọ láti ipa dé ipá títí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan fi farahàn níwájú Ọlọ́run ní Sioni. Gbọ́ àdúrà mi, OLúWA Ọlọ́run Alágbára; tẹ́tí sí mi, Ọlọ́run Jakọbu.