O. Daf 84:5-8
O. Daf 84:5-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ibukún ni fun enia na, ipá ẹniti o wà ninu rẹ: li ọkàn ẹniti ọ̀na rẹ wà. Awọn ti nla afonifoji omije lọ, nwọn sọ ọ di kanga; akọrọ-òjo si fi ibukún bò o. Nwọn nlọ lati ipá de ipá, ni Sioni ni awọn yọ niwaju Ọlọrun. Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, gbọ́ adura mi; fi eti si i, Ọlọrun Jakobu.
O. Daf 84:5-8 Yoruba Bible (YCE)
Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo àwọn tí ó fi ọ́ ṣe agbára wọn, tí ìrìn àjò sí Sioni jẹ wọ́n lógún. Bí wọ́n ti ń la àfonífojì Baka lọ, wọ́n ń sọ ọ́ di orísun omi; àkọ́rọ̀ òjò sì mú kí adágún omi kún ibẹ̀. Wọn ó máa ní agbára kún agbára, títí wọn ó fi farahàn níwájú Ọlọrun ní Sioni. OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, gbọ́ adura mi; tẹ́tí sílẹ̀, Ọlọrun Jakọbu!
O. Daf 84:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Ìbùkún ni fún àwọn tí agbára wọn wà nínú rẹ àwọn tí wọ́n gbé ọkàn lé bíbẹ ibi mímọ́ wò. Àwọn tí ń la àfonífojì omijé lọ wọn sọ ọ́ di kànga àkọ́rọ̀ òjò sì fi ìbùkún bò ó. Wọ́n ń lọ láti ipa dé ipá títí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan fi farahàn níwájú Ọlọ́run ní Sioni. Gbọ́ àdúrà mi, OLúWA Ọlọ́run Alágbára; tẹ́tí sí mi, Ọlọ́run Jakọbu.
