ORIN DAFIDI 84:5-8

ORIN DAFIDI 84:5-8 YCE

Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo àwọn tí ó fi ọ́ ṣe agbára wọn, tí ìrìn àjò sí Sioni jẹ wọ́n lógún. Bí wọ́n ti ń la àfonífojì Baka lọ, wọ́n ń sọ ọ́ di orísun omi; àkọ́rọ̀ òjò sì mú kí adágún omi kún ibẹ̀. Wọn ó máa ní agbára kún agbára, títí wọn ó fi farahàn níwájú Ọlọrun ní Sioni. OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, gbọ́ adura mi; tẹ́tí sílẹ̀, Ọlọrun Jakọbu!