Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ mi;
tẹ́tí rẹ sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
Èmi ó la ẹnu mi ní òwe,
èmi o sọ ohun ìkọ̀kọ̀, ohun ti ọjọ́ pípẹ́;
Ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀,
ohun tí àwọn baba wa ti sọ fún wa.
Àwa kì yóò pa wọ́n mọ́
kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ,
ní fífi ìyìn OLúWA, àti ipa rẹ̀
àti iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣe hàn
fún ìran tí ń bọ̀.
Ó gbé ẹ̀rí kalẹ̀ ní Jakọbu
o sì fìdí àṣẹ múlẹ̀ ní Israẹli,
èyí tí ó pàṣẹ fún àwọn baba ńlá wa
láti kọ́ àwọn ọmọ wọn,
Nítorí náà, àwọn ìran tí ń bọ̀ yóò mọ̀ wọ́n
bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí
tí yóò dìde tí wọn yóò sọ fún àwọn ọmọ wọn
Nígbà náà ni wọ́n ò fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú Ọlọ́run
wọn kò sì ní gbàgbé iṣẹ́ Ọlọ́run
ṣùgbọ́n wọn ó pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
Kí wọn kí ó má ṣe dàbí àwọn baba ńlá wọn,
ìran alágídí àti ọlọ́tẹ̀,
ìran tí ọkàn wọn kò ṣọ òtítọ́ si olóore,
àti ẹ̀mí ẹni tí kò bá Ọlọ́run dúró ṣinṣin.
Àwọn ọkùnrin Efraimu, tí ó há mọ́ ọ tí wọ́n mú ọrun,
wọ́n yípadà ní ọjọ́ ogun
Wọn kò pa májẹ̀mú Ọlọ́run mọ́
wọn sì kọ̀ láti máa gbé nínú òfin rẹ̀
Wọ́n gbàgbé ohun tí ó ti ṣe,
àwọn ìyanu tí ó ti fihàn wọ́n.
Ó ṣe ìyanu níwájú àwọn baba wọn ní ilẹ̀ Ejibiti, ní agbègbè Ṣoani.
Ó pín Òkun ní yà, ó sì mú wọn kọjá
Ó mù kí omi naà dúró bi odi gíga.
Ní ọ̀sán, ó fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ ṣe amọ̀nà wọn
àti ní gbogbo òru pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ iná.
Ó sán àpáta ní aginjù
ó sì fún wọn ní omi mímu lọ́pọ̀lọpọ̀
bí ẹni pé láti inú ibú wá.
Ó mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta
omi ṣíṣàn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí odò.
Wọ́n sì tún tẹ̀síwájú láti dẹ́ṣẹ̀ sí i
ní ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo ní aginjù.
Wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ dán Ọlọ́run wò
nípa bíbéèrè fún oúnjẹ tí wọn bẹ̀bẹ̀ fún
Wọ́n sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, wí pé
“Ọlọ́run ha lè tẹ́ tábìlì ní aginjù?
Nígbà tí ó lu àpáta, omi tú jáde,
odò sì sàn lọ́pọ̀lọpọ̀
ṣùgbọ́n òun ha lè fún wa lóúnjẹ
ó ha le pèsè ẹran fún àwọn ènìyàn rẹ̀”
Nígbà tí OLúWA gbọ́ wọn, ó bínú gidigidi;
iná rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ sí Jakọbu,
ìbínú rẹ̀ sì rú sí Israẹli,
Nítorí wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́,
wọn kò sì gbẹ́kẹ̀lé ìgbàlà rẹ̀.
Síbẹ̀ ó pàṣẹ fún ìràwọ̀ ojú ọ̀run,
ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀;
Ó rọ manna fún àwọn ènìyàn láti jẹ,
ó fún wọn ní ọkà láti ọ̀run.
Àwọn ènìyàn jẹ oúnjẹ àwọn angẹli;
Ó fún wọn ní oúnjẹ ní àjẹyó,
Ó mú afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn láti ọ̀run wá
ó mú afẹ́fẹ́ gúúsù wá nípa agbára rẹ̀.
Ó rọ òjò ẹran sílẹ̀ sórí wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀,
àti ẹyẹ abìyẹ́ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn etí Òkun
Ó jẹ́ kí wọn jáde ní ibùdó wọn,
yíká àgọ́ wọn.
Wọ́n jẹ, wọ́n sì yó jọjọ
nítorí ó ti fún wọn ní ohun tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún
Ṣùgbọ́n wọn kò kúrò nínú oúnjẹ tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún,
nígbà tí oúnjẹ wọn sì wà ní ẹnu wọn,
Ìbínú Ọlọ́run dìde sí wọn
ó pa àwọn tí ó jùlọ nínú wọn,
ó sì lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Israẹli bolẹ̀.