FI eti silẹ, ẹnyin enia mi, si ofin mi: dẹ eti nyin silẹ si ọ̀rọ ẹnu mi.
Emi o ya ẹnu mi li owe: emi o sọ ọ̀rọ atijọ ti o ṣokunkun jade.
Ti awa ti gbọ́, ti a si ti mọ̀, ti awọn baba wa si ti sọ fun wa.
Awa kì yio pa wọn mọ́ kuro lọdọ awọn ọmọ wọn, ni fifi iyìn Oluwa, ati ipa rẹ̀, ati iṣẹ iyanu ti o ti ṣe hàn fun iran ti mbọ.
Nitori ti o gbé ẹri kalẹ ni Jakobu, o si sọ ofin kan ni Israeli, ti o ti pa li aṣẹ fun awọn baba wa pe, ki nwọn ki o le sọ wọn di mimọ̀ fun awọn ọmọ wọn.
Ki awọn iran ti mbọ̀ ki o le mọ̀, ani awọn ọmọ ti a o bi: ti yio si dide, ti yio si sọ fun awọn ọmọ wọn:
Ki nwọn ki o le ma gbé ireti wọn le Ọlọrun, ki nwọn ki o má si ṣe gbagbe iṣẹ Ọlọrun, ṣugbọn ki nwọn ki o pa ofin rẹ̀ mọ́.
Ki nwọn ki o máṣe dabi awọn baba wọn, iran alagidi ati ọlọ̀tẹ̀; iran ti kò fi ọkàn wọn le otitọ, ati ẹmi ẹniti kò ba Ọlọrun duro ṣinṣin.
Awọn ọmọ Efraimu ti o hamọra ogun, ti nwọn mu ọrun, nwọn yipada li ọjọ ogun.
Nwọn kò pa majẹmu Ọlọrun mọ́, nwọn si kọ̀ lati ma rìn ninu ofin rẹ̀.
Nwọn si gbagbe iṣẹ rẹ̀, ati ohun iyanu rẹ̀, ti o ti fi hàn fun wọn.
Ohun iyanu ti o ṣe niwaju awọn baba wọn ni ilẹ Egipti, ani ni igbẹ Soani.
O pin okun ni ìya, o si mu wọn là a ja; o si mu omi duro bi bèbe.
Li ọsan pẹlu o fi awọsanma ṣe amọna wọn, ati li oru gbogbo pẹlu imọlẹ iná.
O sán apata li aginju, o si fun wọn li omi mímu lọpọlọpọ bi ẹnipe lati inu ibú wá.
O si mu iṣàn-omi jade wá lati inu apata, o si mu omi ṣàn silẹ bi odò nla.
Nwọn si tún ṣẹ̀ si i; ni ṣiṣọtẹ si Ọga-ogo li aginju.
Nwọn si dán Ọlọrun wò li ọkàn wọn, ni bibère onjẹ fun ifẹkufẹ wọn.
Nwọn si sọ̀rọ si Ọlọrun; nwọn wipe, Ọlọrun ha le tẹ́ tabili li aginju?
Wò o! o lù apata, omi si tú jade, iṣàn-omi si kún pupọ; o ha le funni li àkara pẹlu? o ha le pèse ẹran fun awọn enia rẹ̀?
Nitorina, Oluwa gbọ́ eyi, o binu: bẹ̃ni iná ràn ni Jakobu, ibinu si ru ni Israeli;
Nitori ti nwọn kò gbà Ọlọrun gbọ́, nwọn kò si gbẹkẹle igbala rẹ̀.
O paṣẹ fun awọsanma lati òke wá, o si ṣi ilẹkùn ọrun silẹ.
O si rọ̀jo Manna silẹ fun wọn ni jijẹ, o si fun wọn li ọkà ọrun.
Enia jẹ onjẹ awọn angeli; o rán onjẹ si wọn li ajẹyo.
O mu afẹfẹ ìla-õrun fẹ li ọrun, ati nipa agbara rẹ̀ o mu afẹfẹ gusu wá.
O rọ̀jo ẹran si wọn pẹlu bi erupẹ ilẹ, ati ẹiyẹ abiyẹ bi iyanrin okun.
O si jẹ ki o bọ́ si ãrin ibudo wọn, yi agọ wọn ka.
Bẹ̃ni nwọn jẹ, nwọn si yo jọjọ: nitoriti o fi ifẹ wọn fun wọn.
Nwọn kò kuro ninu ifẹkufẹ wọn; nigbati onjẹ wọn si wà li ẹnu wọn.
Ibinu Ọlọrun de si ori wọn, o pa awọn ti o sanra ninu wọn, o si lù awọn ọdọmọkunrin Israeli bolẹ.