O. Daf 78:1-31

O. Daf 78:1-31 Bibeli Mimọ (YBCV)

FI eti silẹ, ẹnyin enia mi, si ofin mi: dẹ eti nyin silẹ si ọ̀rọ ẹnu mi. Emi o ya ẹnu mi li owe: emi o sọ ọ̀rọ atijọ ti o ṣokunkun jade. Ti awa ti gbọ́, ti a si ti mọ̀, ti awọn baba wa si ti sọ fun wa. Awa kì yio pa wọn mọ́ kuro lọdọ awọn ọmọ wọn, ni fifi iyìn Oluwa, ati ipa rẹ̀, ati iṣẹ iyanu ti o ti ṣe hàn fun iran ti mbọ. Nitori ti o gbé ẹri kalẹ ni Jakobu, o si sọ ofin kan ni Israeli, ti o ti pa li aṣẹ fun awọn baba wa pe, ki nwọn ki o le sọ wọn di mimọ̀ fun awọn ọmọ wọn. Ki awọn iran ti mbọ̀ ki o le mọ̀, ani awọn ọmọ ti a o bi: ti yio si dide, ti yio si sọ fun awọn ọmọ wọn: Ki nwọn ki o le ma gbé ireti wọn le Ọlọrun, ki nwọn ki o má si ṣe gbagbe iṣẹ Ọlọrun, ṣugbọn ki nwọn ki o pa ofin rẹ̀ mọ́. Ki nwọn ki o máṣe dabi awọn baba wọn, iran alagidi ati ọlọ̀tẹ̀; iran ti kò fi ọkàn wọn le otitọ, ati ẹmi ẹniti kò ba Ọlọrun duro ṣinṣin. Awọn ọmọ Efraimu ti o hamọra ogun, ti nwọn mu ọrun, nwọn yipada li ọjọ ogun. Nwọn kò pa majẹmu Ọlọrun mọ́, nwọn si kọ̀ lati ma rìn ninu ofin rẹ̀. Nwọn si gbagbe iṣẹ rẹ̀, ati ohun iyanu rẹ̀, ti o ti fi hàn fun wọn. Ohun iyanu ti o ṣe niwaju awọn baba wọn ni ilẹ Egipti, ani ni igbẹ Soani. O pin okun ni ìya, o si mu wọn là a ja; o si mu omi duro bi bèbe. Li ọsan pẹlu o fi awọsanma ṣe amọna wọn, ati li oru gbogbo pẹlu imọlẹ iná. O sán apata li aginju, o si fun wọn li omi mímu lọpọlọpọ bi ẹnipe lati inu ibú wá. O si mu iṣàn-omi jade wá lati inu apata, o si mu omi ṣàn silẹ bi odò nla. Nwọn si tún ṣẹ̀ si i; ni ṣiṣọtẹ si Ọga-ogo li aginju. Nwọn si dán Ọlọrun wò li ọkàn wọn, ni bibère onjẹ fun ifẹkufẹ wọn. Nwọn si sọ̀rọ si Ọlọrun; nwọn wipe, Ọlọrun ha le tẹ́ tabili li aginju? Wò o! o lù apata, omi si tú jade, iṣàn-omi si kún pupọ; o ha le funni li àkara pẹlu? o ha le pèse ẹran fun awọn enia rẹ̀? Nitorina, Oluwa gbọ́ eyi, o binu: bẹ̃ni iná ràn ni Jakobu, ibinu si ru ni Israeli; Nitori ti nwọn kò gbà Ọlọrun gbọ́, nwọn kò si gbẹkẹle igbala rẹ̀. O paṣẹ fun awọsanma lati òke wá, o si ṣi ilẹkùn ọrun silẹ. O si rọ̀jo Manna silẹ fun wọn ni jijẹ, o si fun wọn li ọkà ọrun. Enia jẹ onjẹ awọn angeli; o rán onjẹ si wọn li ajẹyo. O mu afẹfẹ ìla-õrun fẹ li ọrun, ati nipa agbara rẹ̀ o mu afẹfẹ gusu wá. O rọ̀jo ẹran si wọn pẹlu bi erupẹ ilẹ, ati ẹiyẹ abiyẹ bi iyanrin okun. O si jẹ ki o bọ́ si ãrin ibudo wọn, yi agọ wọn ka. Bẹ̃ni nwọn jẹ, nwọn si yo jọjọ: nitoriti o fi ifẹ wọn fun wọn. Nwọn kò kuro ninu ifẹkufẹ wọn; nigbati onjẹ wọn si wà li ẹnu wọn. Ibinu Ọlọrun de si ori wọn, o pa awọn ti o sanra ninu wọn, o si lù awọn ọdọmọkunrin Israeli bolẹ.

O. Daf 78:1-31 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ̀yin eniyan mi, ẹ dẹtí sí ẹ̀kọ́ mi; ẹ tẹ́tí si ọ̀rọ̀ ẹnu mi. N óo la ẹnu mi tòwe-tòwe; n óo fa ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ àtijọ́ yọ, ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀, ohun tí àwọn baba ńlá wa ti sọ fún wa. A kò ní fi pamọ́ fún àwọn ọmọ wọn; a óo máa sọ ọ́ fún àwọn ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn– iṣẹ́ ńlá OLUWA ati ìṣe akọni rẹ̀, ati iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe. Ó fi ìlànà lélẹ̀ fún ìdílé Jakọbu; ó gbé òfin kalẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli. Ó pa á láṣẹ fún àwọn baba ńlá wa, pé kí wọ́n fi kọ́ àwọn ọmọ wọn. Kí àwọn ìran tí ń bọ̀ lè mọ̀ ọ́n, àní, àwọn ọmọ tí a kò tíì bí, kí àwọn náà ní ìgbà tiwọn lè sọ ọ́ fún àwọn ọmọ wọn. Kí wọn lè gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun, kí wọn má gbàgbé iṣẹ́ rẹ̀, kí wọn sì máa pa òfin rẹ̀ mọ́, kí wọn má dàbí àwọn baba ńlá wọn, ìran àwọn olóríkunkun ati ọlọ̀tẹ̀, àwọn tí ọkàn wọn kò dúró ṣinṣin, tí ẹ̀mí wọn kò sì dúró gbọningbọnin ti Olodumare. Àwọn ọmọ Efuraimu kó ọrun, wọ́n kó ọfà, ṣugbọn wọ́n pẹ̀yìndà lọ́jọ́ ìjà. Wọn kò pa majẹmu Ọlọrun mọ́, wọ́n kọ̀, wọn kò jẹ́ pa òfin rẹ̀ mọ́. Wọ́n gbàgbé iṣẹ́ rẹ̀, ati iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe hàn wọ́n. Ní ìṣojú àwọn baba ńlá wọn, ó ṣe ohun ìyanu, ní ilẹ̀ Ijipti, ní oko Soani. Ó pín òkun níyà, ó jẹ́ kí wọ́n kọjá láàrin rẹ̀; ó sì mú kí omi nàró bí òpó ńlá. Ó fi ìkùukùu ṣe atọ́nà wọn ní ọ̀sán, ó fi ìmọ́lẹ̀ iná tọ́ wọn sọ́nà ní gbogbo òru. Ó la àpáta ni aṣálẹ̀, ó sì fún wọn ní omi mu lọpọlọpọ bí ẹni pé láti inú ibú. Ó mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta; ó sì mú kí ó ṣàn bí odò. Sibẹsibẹ wọn ò dẹ́kun ẹ̀ṣẹ̀ dídá; wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá Ògo ninu aṣálẹ̀. Wọ́n dán Ọlọrun wò ninu ọkàn wọn, wọ́n ń wá oúnjẹ tí yóo tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn. Wọ́n sọ̀rọ̀ ìwọ̀sí sí Ọlọrun, wọ́n ní, “Ṣé Ọlọrun lè gbé oúnjẹ kalẹ̀ fún wa ninu aṣálẹ̀? Lóòótọ́ ó lu òkúta tí omi fi tú jáde, tí odò sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn. Ṣé ó lè fún wa ní òkèlè pẹlu, àbí ó lè pèsè ẹran fún àwọn eniyan rẹ̀?” Nítorí náà nígbà tí OLUWA gbọ́, inú bí i; iná mọ́ ìdílé Jakọbu, inú OLUWA sì ru sí àwọn ọmọ Israẹli; nítorí pé wọn kò gba Ọlọrun gbọ́; wọn kò sì gbẹ́kẹ̀lé agbára ìgbàlà rẹ̀. Sibẹ ó pàṣẹ fún ìkùukùu lókè, ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀. Ó rọ òjò mana sílẹ̀ fún wọn láti jẹ, ó sì fún wọn ní ọkà ọ̀run. Ọmọ eniyan jẹ lára oúnjẹ àwọn angẹli; Ọlọrun fún wọn ní oúnjẹ àjẹtẹ́rùn. Ó mú kí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn fẹ́ ní ojú ọ̀run, ó sì fi agbára rẹ̀ darí afẹ́fẹ́ ìhà gúsù; ó sì rọ̀jò ẹran sílẹ̀ fún wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀; àní, ẹyẹ abìyẹ́ bíi yanrìn etí òkun. Ó mú kí wọn bọ́ sílẹ̀ láàrin ibùdó; yíká gbogbo àgọ́ wọn, Àwọn eniyan náà jẹ, wọ́n sì yó; nítorí pé Ọlọrun fún wọn ní ohun tí ọkàn wọn fẹ́. Ṣugbọn kí wọn tó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn, àní, nígbà tí wọn ṣì ń jẹun lọ́wọ́. Ọlọrun bínú sí wọn; ó pa àwọn tí ó lágbára jùlọ ninu wọn, ó sì lu àṣàyàn àwọn ọdọmọkunrin Israẹli pa.

O. Daf 78:1-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ mi; tẹ́tí rẹ sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi. Èmi ó la ẹnu mi ní òwe, èmi o sọ ohun ìkọ̀kọ̀, ohun ti ọjọ́ pípẹ́; Ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀, ohun tí àwọn baba wa ti sọ fún wa. Àwa kì yóò pa wọ́n mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ, ní fífi ìyìn OLúWA, àti ipa rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣe hàn fún ìran tí ń bọ̀. Ó gbé ẹ̀rí kalẹ̀ ní Jakọbu o sì fìdí àṣẹ múlẹ̀ ní Israẹli, èyí tí ó pàṣẹ fún àwọn baba ńlá wa láti kọ́ àwọn ọmọ wọn, Nítorí náà, àwọn ìran tí ń bọ̀ yóò mọ̀ wọ́n bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí tí yóò dìde tí wọn yóò sọ fún àwọn ọmọ wọn Nígbà náà ni wọ́n ò fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú Ọlọ́run wọn kò sì ní gbàgbé iṣẹ́ Ọlọ́run ṣùgbọ́n wọn ó pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. Kí wọn kí ó má ṣe dàbí àwọn baba ńlá wọn, ìran alágídí àti ọlọ́tẹ̀, ìran tí ọkàn wọn kò ṣọ òtítọ́ si olóore, àti ẹ̀mí ẹni tí kò bá Ọlọ́run dúró ṣinṣin. Àwọn ọkùnrin Efraimu, tí ó há mọ́ ọ tí wọ́n mú ọrun, wọ́n yípadà ní ọjọ́ ogun Wọn kò pa májẹ̀mú Ọlọ́run mọ́ wọn sì kọ̀ láti máa gbé nínú òfin rẹ̀ Wọ́n gbàgbé ohun tí ó ti ṣe, àwọn ìyanu tí ó ti fihàn wọ́n. Ó ṣe ìyanu níwájú àwọn baba wọn ní ilẹ̀ Ejibiti, ní agbègbè Ṣoani. Ó pín Òkun ní yà, ó sì mú wọn kọjá Ó mù kí omi naà dúró bi odi gíga. Ní ọ̀sán, ó fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ ṣe amọ̀nà wọn àti ní gbogbo òru pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ iná. Ó sán àpáta ní aginjù ó sì fún wọn ní omi mímu lọ́pọ̀lọpọ̀ bí ẹni pé láti inú ibú wá. Ó mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta omi ṣíṣàn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí odò. Wọ́n sì tún tẹ̀síwájú láti dẹ́ṣẹ̀ sí i ní ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo ní aginjù. Wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ dán Ọlọ́run wò nípa bíbéèrè fún oúnjẹ tí wọn bẹ̀bẹ̀ fún Wọ́n sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, wí pé “Ọlọ́run ha lè tẹ́ tábìlì ní aginjù? Nígbà tí ó lu àpáta, omi tú jáde, odò sì sàn lọ́pọ̀lọpọ̀ ṣùgbọ́n òun ha lè fún wa lóúnjẹ ó ha le pèsè ẹran fún àwọn ènìyàn rẹ̀” Nígbà tí OLúWA gbọ́ wọn, ó bínú gidigidi; iná rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ sí Jakọbu, ìbínú rẹ̀ sì rú sí Israẹli, Nítorí wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́, wọn kò sì gbẹ́kẹ̀lé ìgbàlà rẹ̀. Síbẹ̀ ó pàṣẹ fún ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀; Ó rọ manna fún àwọn ènìyàn láti jẹ, ó fún wọn ní ọkà láti ọ̀run. Àwọn ènìyàn jẹ oúnjẹ àwọn angẹli; Ó fún wọn ní oúnjẹ ní àjẹyó, Ó mú afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn láti ọ̀run wá ó mú afẹ́fẹ́ gúúsù wá nípa agbára rẹ̀. Ó rọ òjò ẹran sílẹ̀ sórí wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀, àti ẹyẹ abìyẹ́ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn etí Òkun Ó jẹ́ kí wọn jáde ní ibùdó wọn, yíká àgọ́ wọn. Wọ́n jẹ, wọ́n sì yó jọjọ nítorí ó ti fún wọn ní ohun tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún Ṣùgbọ́n wọn kò kúrò nínú oúnjẹ tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún, nígbà tí oúnjẹ wọn sì wà ní ẹnu wọn, Ìbínú Ọlọ́run dìde sí wọn ó pa àwọn tí ó jùlọ nínú wọn, ó sì lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Israẹli bolẹ̀.