Ẹ̀yin eniyan mi, ẹ dẹtí sí ẹ̀kọ́ mi;
ẹ tẹ́tí si ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
N óo la ẹnu mi tòwe-tòwe;
n óo fa ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ àtijọ́ yọ,
ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀,
ohun tí àwọn baba ńlá wa ti sọ fún wa.
A kò ní fi pamọ́ fún àwọn ọmọ wọn;
a óo máa sọ ọ́ fún àwọn ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn–
iṣẹ́ ńlá OLUWA ati ìṣe akọni rẹ̀,
ati iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe.
Ó fi ìlànà lélẹ̀ fún ìdílé Jakọbu;
ó gbé òfin kalẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli.
Ó pa á láṣẹ fún àwọn baba ńlá wa,
pé kí wọ́n fi kọ́ àwọn ọmọ wọn.
Kí àwọn ìran tí ń bọ̀ lè mọ̀ ọ́n,
àní, àwọn ọmọ tí a kò tíì bí,
kí àwọn náà ní ìgbà tiwọn
lè sọ ọ́ fún àwọn ọmọ wọn.
Kí wọn lè gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun,
kí wọn má gbàgbé iṣẹ́ rẹ̀,
kí wọn sì máa pa òfin rẹ̀ mọ́,
kí wọn má dàbí àwọn baba ńlá wọn,
ìran àwọn olóríkunkun ati ọlọ̀tẹ̀,
àwọn tí ọkàn wọn kò dúró ṣinṣin,
tí ẹ̀mí wọn kò sì dúró gbọningbọnin ti Olodumare.
Àwọn ọmọ Efuraimu kó ọrun, wọ́n kó ọfà,
ṣugbọn wọ́n pẹ̀yìndà lọ́jọ́ ìjà.
Wọn kò pa majẹmu Ọlọrun mọ́,
wọ́n kọ̀, wọn kò jẹ́ pa òfin rẹ̀ mọ́.
Wọ́n gbàgbé iṣẹ́ rẹ̀,
ati iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe hàn wọ́n.
Ní ìṣojú àwọn baba ńlá wọn, ó ṣe ohun ìyanu,
ní ilẹ̀ Ijipti, ní oko Soani.
Ó pín òkun níyà, ó jẹ́ kí wọ́n kọjá láàrin rẹ̀;
ó sì mú kí omi nàró bí òpó ńlá.
Ó fi ìkùukùu ṣe atọ́nà wọn ní ọ̀sán,
ó fi ìmọ́lẹ̀ iná tọ́ wọn sọ́nà ní gbogbo òru.
Ó la àpáta ni aṣálẹ̀,
ó sì fún wọn ní omi mu lọpọlọpọ bí ẹni pé láti inú ibú.
Ó mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta;
ó sì mú kí ó ṣàn bí odò.
Sibẹsibẹ wọn ò dẹ́kun ẹ̀ṣẹ̀ dídá;
wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá Ògo ninu aṣálẹ̀.
Wọ́n dán Ọlọrun wò ninu ọkàn wọn,
wọ́n ń wá oúnjẹ tí yóo tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn.
Wọ́n sọ̀rọ̀ ìwọ̀sí sí Ọlọrun, wọ́n ní,
“Ṣé Ọlọrun lè gbé oúnjẹ kalẹ̀ fún wa ninu aṣálẹ̀?
Lóòótọ́ ó lu òkúta tí omi fi tú jáde,
tí odò sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn.
Ṣé ó lè fún wa ní òkèlè pẹlu,
àbí ó lè pèsè ẹran fún àwọn eniyan rẹ̀?”
Nítorí náà nígbà tí OLUWA gbọ́,
inú bí i;
iná mọ́ ìdílé Jakọbu,
inú OLUWA sì ru sí àwọn ọmọ Israẹli;
nítorí pé wọn kò gba Ọlọrun gbọ́;
wọn kò sì gbẹ́kẹ̀lé agbára ìgbàlà rẹ̀.
Sibẹ ó pàṣẹ fún ìkùukùu lókè,
ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀.
Ó rọ òjò mana sílẹ̀
fún wọn láti jẹ,
ó sì fún wọn ní ọkà ọ̀run.
Ọmọ eniyan jẹ lára oúnjẹ àwọn angẹli;
Ọlọrun fún wọn ní oúnjẹ àjẹtẹ́rùn.
Ó mú kí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn fẹ́ ní ojú ọ̀run,
ó sì fi agbára rẹ̀ darí afẹ́fẹ́ ìhà gúsù;
ó sì rọ̀jò ẹran sílẹ̀ fún wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀;
àní, ẹyẹ abìyẹ́ bíi yanrìn etí òkun.
Ó mú kí wọn bọ́ sílẹ̀ láàrin ibùdó;
yíká gbogbo àgọ́ wọn,
Àwọn eniyan náà jẹ, wọ́n sì yó;
nítorí pé Ọlọrun fún wọn ní ohun tí ọkàn wọn fẹ́.
Ṣugbọn kí wọn tó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn,
àní, nígbà tí wọn ṣì ń jẹun lọ́wọ́.
Ọlọrun bínú sí wọn;
ó pa àwọn tí ó lágbára jùlọ ninu wọn,
ó sì lu àṣàyàn àwọn ọdọmọkunrin Israẹli pa.