Saamu 7:1-17

Saamu 7:1-17 YCB

OLúWA Ọlọ́run mi, ààbò mi wà nínú rẹ; gba mí là kí o sì tú mi sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó ń lé mi, kí wọn ó má ba à fa ọkàn mi ya gẹ́gẹ́ bí kìnnìún, wọ́n á ya á pẹ́rẹpẹ̀rẹ láìsí ẹni tí yóò gbà mí. OLúWA Ọlọ́run mi, tí èmi bá ṣe èyí tí ẹ̀bi sì wà ní ọwọ́ mi Bí èmi bá ṣe ibi sí ẹni tí ń wá àlàáfíà pẹ̀lú mi, tí mo ja ọ̀tá mi lólè láìnídìí: Nígbà náà, jẹ́ kí ọ̀tá mi lé mi kí wọn sì mú mi; jẹ́ kí òun kí ó tẹ ọkàn mi mọ́lẹ̀ kí wọn sì mú mi sùn nínú eruku. Sela. Dìde, OLúWA, nínú ìbínú rẹ; dìde lòdì sí ìrunú àwọn ọ̀tá mi. Jí, Ọlọ́run mi; kéde òdodo. Kí ìpéjọ àwọn ènìyàn yíká. Jọba lórí wọn láti òkè wá; Jẹ́ kí OLúWA ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn. Ṣe ìdájọ́ mi, OLúWA, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi, gẹ́gẹ́ bí ìwà òtítọ́, ẹni gíga jùlọ. Ọlọ́run Olódodo, Ẹni tí ó ń wo inú àti ọkàn, tí ó ń mú òpin sí ìwà ipá ẹni búburú tí ó sì ń pa àwọn olódodo mọ́. Ààbò mi ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ń ṣe ìgbàlà òtítọ́ ní àyà. Ọlọ́run ni onídàájọ́ òtítọ́, Ọlọ́run tí ń sọ ìrunú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́. Bí kò bá yípadà, Òun yóò pọ́n idà rẹ̀ mú; ó ti fa ọrun rẹ̀ le ná, ó ti múra rẹ̀ sílẹ̀. Ó ti pèsè ohun ìjà ikú sílẹ̀; ó ti pèsè ọfà iná sílẹ̀. Ẹni tí ó lóyún ohun búburú, tí ó sì lóyún wàhálà, ó bí èké jáde. Ẹni tí ó gbẹ́ ọ̀fìn, tí ó kó o jáde jì sí kòtò tí ó gbẹ́ sílẹ̀. Wàhálà tí ó fà padà sórí rẹ̀; Ìwà ipá rẹ̀ padà sórí ara rẹ̀. Èmi ó fi ọpẹ́ fún OLúWA nítorí òdodo rẹ̀, Èmi ó kọrin ìyìn sí OLúWA Ọ̀gá-ògo jùlọ.