OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni mo sá di;
gbà mí là, kí o sì yọ mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi.
Kí wọn má baà fà mí ya bíi kinniun,
kí wọn máa wọ́ mi lọ láìsí ẹni tí ó lè gbà mí sílẹ̀.
OLUWA, Ọlọrun mi, bí mo bá ṣe nǹkan yìí,
bí iṣẹ́ ibi bá ń bẹ lọ́wọ́ mi,
bí mo bá fi ibi san án fún olóore,
tabi tí mo bá kó ọ̀tá mi lẹ́rú láìnídìí,
jẹ́ kí ọ̀tá ó lé mi bá,
kí ó tẹ̀ mí pa,
kí ó sì bo òkú mi mọ́ ilẹ̀ẹ́lẹ̀.
OLUWA, fi ibinu dìde!
Gbéra, kí o bá àwọn ọ̀tá mi jà ninu ìrúnú wọn;
jí gìrì, Ọlọrun mi; ìwọ ni o ti fi ìlànà òdodo lélẹ̀.
Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè ayé ó rọ̀gbà yí ọ ká,
kí o sì máa jọba lé wọn lórí láti òkè wá.
OLUWA ló ń ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ayé;
dá mi láre, OLUWA, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi ati ìwà pípé mi.
Ìwọ Ọlọrun Olódodo, tí o mọ èrò ati ìfẹ́ inú eniyan,
fi òpin sí ìwà ibi àwọn eniyan burúkú,
kí o sì fi ìdí àwọn olódodo múlẹ̀.
Ọlọrun ni aláàbò mi,
òun níí gba àwọn ọlọ́kàn mímọ́ là.
Onídàájọ́ òdodo ni Ọlọrun,
a sì máa bínú sí àwọn aṣebi lojoojumọ.
Bí wọn kò bá yipada, Ọlọrun yóo pọ́n idà rẹ̀;
ó ti tẹ ọrun rẹ̀, ó sì ti fi ọfà lé e.
Ó ti pèsè ohun ìjà ikú sílẹ̀,
ó sì ti tọ́jú ọfà iná.
Wò ó, eniyan burúkú lóyún ibi, ó lóyún ìkà, ó sì bí èké.
Ó gbẹ́ kòtò,
ó sì jìn sinu kòtò tí ó gbẹ́.
Ìkà rẹ̀ pada sórí ara rẹ̀,
àní ìwà ipá rẹ̀ sì já lù ú ní àtàrí.
N óo fi ọpẹ́ tí ó yẹ fún OLUWA nítorí òdodo rẹ̀,
n óo fi orin ìyìn kí OLUWA, Ọ̀gá Ògo.