O. Daf 7:1-17

O. Daf 7:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUWA, Ọlọrun mi, iwọ ni mo gbẹkẹ mi le: gbà mi lọwọ gbogbo awọn ti nṣe inunibini si mi, ki o si yọ mi kuro. Ki o má ba fa ọkàn mi ya bi kiniun, a yà a pẹrẹpẹrẹ, nigbati kò si oluranlọwọ. Oluwa, Ọlọrun mi, bi mo ba ṣe eyi, bi ẹ̀ṣẹ ba mbẹ li ọwọ mi; Bi mo ba fi ibi san a fun ẹniti temi tirẹ̀ wà li alafia; (nitõtọ ẹniti nṣe ọta mi li ainidi, emi tilẹ gbà a là:) Jẹ ki ọta ki o ṣe inunibini si ọkàn mi, ki o si mu u; ki o tẹ̀ ẹmi mi mọlẹ, ki o si fi ọlá mi le inu ekuru. Dide Oluwa, ni ibinu rẹ! gbé ara rẹ soke nitori ikannu awọn ọta mi: ki iwọ ki o si jí fun mi si idajọ ti iwọ ti pa li aṣẹ. Bẹ̃ni ijọ awọn enia yio yi ọ ká kiri; njẹ nitori wọn iwọ pada si òke. Oluwa yio ṣe idajọ awọn enia: Oluwa ṣe idajọ mi, gẹgẹ bi ododo mi, ati gẹgẹ bi ìwatitọ inu mi. Jẹ ki ìwa-buburu awọn enia buburu ki o de opin: ṣugbọn mu olotitọ duro: nitoriti Ọlọrun olododo li o ndan aiya ati inu wò. Abo mi mbẹ lọdọ Ọlọrun ti o nṣe igbala olotitọ li aiya. Ọlọrun li onidajọ ododo, Ọlọrun si nbinu si enia buburu lojojumọ: Bi on kò ba yipada, yio si pọ́n idà rẹ̀ mu: o ti fà ọrun rẹ̀ le na, o ti mura rẹ̀ silẹ. O si ti pèse elo ikú silẹ fun u; o ti ṣe awọn ọfa rẹ̀ ni oniná. Kiyesi i, o nrọbi ẹ̀ṣẹ, o si loyun ìwa-ìka, o si bí eké jade. O ti wà ọ̀fin, o gbẹ́ ẹ, o si bọ́ sinu iho ti on na wà. Ìwa-ika rẹ̀ yio si pada si ori ara rẹ̀, ati ìwa-agbara rẹ̀ yio si sọ̀kalẹ bọ̀ si atari ara rẹ̀. Emi o yìn Oluwa gẹgẹ bi ododo rẹ̀: emi o si kọrin iyìn si orukọ Oluwa Ọga-ogo julọ.

O. Daf 7:1-17 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni mo sá di; gbà mí là, kí o sì yọ mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi. Kí wọn má baà fà mí ya bíi kinniun, kí wọn máa wọ́ mi lọ láìsí ẹni tí ó lè gbà mí sílẹ̀. OLUWA, Ọlọrun mi, bí mo bá ṣe nǹkan yìí, bí iṣẹ́ ibi bá ń bẹ lọ́wọ́ mi, bí mo bá fi ibi san án fún olóore, tabi tí mo bá kó ọ̀tá mi lẹ́rú láìnídìí, jẹ́ kí ọ̀tá ó lé mi bá, kí ó tẹ̀ mí pa, kí ó sì bo òkú mi mọ́ ilẹ̀ẹ́lẹ̀. OLUWA, fi ibinu dìde! Gbéra, kí o bá àwọn ọ̀tá mi jà ninu ìrúnú wọn; jí gìrì, Ọlọrun mi; ìwọ ni o ti fi ìlànà òdodo lélẹ̀. Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè ayé ó rọ̀gbà yí ọ ká, kí o sì máa jọba lé wọn lórí láti òkè wá. OLUWA ló ń ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ayé; dá mi láre, OLUWA, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi ati ìwà pípé mi. Ìwọ Ọlọrun Olódodo, tí o mọ èrò ati ìfẹ́ inú eniyan, fi òpin sí ìwà ibi àwọn eniyan burúkú, kí o sì fi ìdí àwọn olódodo múlẹ̀. Ọlọrun ni aláàbò mi, òun níí gba àwọn ọlọ́kàn mímọ́ là. Onídàájọ́ òdodo ni Ọlọrun, a sì máa bínú sí àwọn aṣebi lojoojumọ. Bí wọn kò bá yipada, Ọlọrun yóo pọ́n idà rẹ̀; ó ti tẹ ọrun rẹ̀, ó sì ti fi ọfà lé e. Ó ti pèsè ohun ìjà ikú sílẹ̀, ó sì ti tọ́jú ọfà iná. Wò ó, eniyan burúkú lóyún ibi, ó lóyún ìkà, ó sì bí èké. Ó gbẹ́ kòtò, ó sì jìn sinu kòtò tí ó gbẹ́. Ìkà rẹ̀ pada sórí ara rẹ̀, àní ìwà ipá rẹ̀ sì já lù ú ní àtàrí. N óo fi ọpẹ́ tí ó yẹ fún OLUWA nítorí òdodo rẹ̀, n óo fi orin ìyìn kí OLUWA, Ọ̀gá Ògo.

O. Daf 7:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

OLúWA Ọlọ́run mi, ààbò mi wà nínú rẹ; gba mí là kí o sì tú mi sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó ń lé mi, kí wọn ó má ba à fa ọkàn mi ya gẹ́gẹ́ bí kìnnìún, wọ́n á ya á pẹ́rẹpẹ̀rẹ láìsí ẹni tí yóò gbà mí. OLúWA Ọlọ́run mi, tí èmi bá ṣe èyí tí ẹ̀bi sì wà ní ọwọ́ mi Bí èmi bá ṣe ibi sí ẹni tí ń wá àlàáfíà pẹ̀lú mi, tí mo ja ọ̀tá mi lólè láìnídìí: Nígbà náà, jẹ́ kí ọ̀tá mi lé mi kí wọn sì mú mi; jẹ́ kí òun kí ó tẹ ọkàn mi mọ́lẹ̀ kí wọn sì mú mi sùn nínú eruku. Sela. Dìde, OLúWA, nínú ìbínú rẹ; dìde lòdì sí ìrunú àwọn ọ̀tá mi. Jí, Ọlọ́run mi; kéde òdodo. Kí ìpéjọ àwọn ènìyàn yíká. Jọba lórí wọn láti òkè wá; Jẹ́ kí OLúWA ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn. Ṣe ìdájọ́ mi, OLúWA, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi, gẹ́gẹ́ bí ìwà òtítọ́, ẹni gíga jùlọ. Ọlọ́run Olódodo, Ẹni tí ó ń wo inú àti ọkàn, tí ó ń mú òpin sí ìwà ipá ẹni búburú tí ó sì ń pa àwọn olódodo mọ́. Ààbò mi ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ń ṣe ìgbàlà òtítọ́ ní àyà. Ọlọ́run ni onídàájọ́ òtítọ́, Ọlọ́run tí ń sọ ìrunú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́. Bí kò bá yípadà, Òun yóò pọ́n idà rẹ̀ mú; ó ti fa ọrun rẹ̀ le ná, ó ti múra rẹ̀ sílẹ̀. Ó ti pèsè ohun ìjà ikú sílẹ̀; ó ti pèsè ọfà iná sílẹ̀. Ẹni tí ó lóyún ohun búburú, tí ó sì lóyún wàhálà, ó bí èké jáde. Ẹni tí ó gbẹ́ ọ̀fìn, tí ó kó o jáde jì sí kòtò tí ó gbẹ́ sílẹ̀. Wàhálà tí ó fà padà sórí rẹ̀; Ìwà ipá rẹ̀ padà sórí ara rẹ̀. Èmi ó fi ọpẹ́ fún OLúWA nítorí òdodo rẹ̀, Èmi ó kọrin ìyìn sí OLúWA Ọ̀gá-ògo jùlọ.