Saamu 119:169-176

Saamu 119:169-176 YCB

Jẹ́ kí igbe mi wá sí iwájú rẹ, OLúWA; fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi wá sí iwájú rẹ; gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ. Ètè mi yóò sọ ìyìn jáde, nítorí ìwọ kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Jẹ́ kí ahọ́n mi kọ orin ọ̀rọ̀ rẹ, nítorí gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òdodo. Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣetán láti ràn mí lọ́wọ́, nítorí èmi ti yan ẹ̀kọ́ rẹ. Èmi wo ọ̀nà fún ìgbàlà rẹ, OLúWA, àti òfin rẹ jẹ́ dídùn inú mi. Jẹ́ kí èmi wà láààyè ki èmi lè yìn ọ́, kí o sì jẹ́ kí òfin rẹ mú mi dúró. Èmí ti ṣìnà bí àgùntàn tí ó sọnù, wá ìránṣẹ́ rẹ, nítorí èmi kò gbàgbé àṣẹ rẹ.