O. Daf 119:169-176

O. Daf 119:169-176 YBCV

Oluwa, jẹ ki ẹkún mi ki o sunmọ iwaju rẹ: fun mi li oye gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Jẹ ki ẹ̀bẹ mi ki o wá siwaju rẹ: gbà mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Ete mi yio sọ iyìn jade, nigbati iwọ ba ti kọ́ mi ni ilana rẹ. Ahọn mi yio sọ niti ọ̀rọ rẹ: nitori pe ododo ni gbogbo aṣẹ rẹ. Jẹ ki ọwọ rẹ ki o ràn mi lọwọ; nitori ti mo ti yàn ẹkọ rẹ. Oluwa, ọkàn mi ti fà si igbala rẹ; ofin rẹ si ni didùn-inu mi. Jẹ ki ọkàn mi ki o wà lãye, yio si ma yìn ọ; si jẹ ki idajọ rẹ ki o ma ràn mi lọwọ. Emi ti ṣina kiri bi agutan ti o nù; wá iranṣẹ rẹ nitori ti emi kò gbagbe aṣẹ rẹ.