ORIN DAFIDI 119:169-176

ORIN DAFIDI 119:169-176 YCE

Jẹ́ kí igbe mi dé ọ̀dọ̀ rẹ, OLUWA, fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi dé iwájú rẹ, kí o sì gbà mí là gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Ẹnu mi yóo kún fún ìyìn rẹ, pé o ti kọ́ mi ní ìlànà rẹ. N óo máa fi ọ̀rọ̀ rẹ ṣe orin kọ, nítorí pé gbogbo òfin rẹ ni ó tọ̀nà. Múra láti ràn mí lọ́wọ́, nítorí pé mo ti gba ẹ̀kọ́ rẹ. Ọkàn mi ń fà sí ìgbàlà rẹ, OLUWA; òfin rẹ sì ni inú dídùn mi. Dá mi sí kí n lè máa yìn ọ́, sì jẹ́ kí òfin rẹ ràn mí lọ́wọ́. Mo ti ṣìnà bí aguntan tó sọnù; wá èmi, iranṣẹ rẹ, rí, nítorí pé n kò gbàgbé òfin rẹ.