Saamu 106:1-12

Saamu 106:1-12 YCB

Yin OLúWA! Ẹ fi ìyìn fún OLúWA, nítorí tí ó ṣeun. Ẹ fi ọpẹ́ fún OLúWA nítorí tí ó ṣeun; Nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé. Ta ni ó lè ròyìn iṣẹ́ agbára OLúWA, ta ní lè sọ nípa ìyìn rẹ̀? Ìbùkún ni fún àwọn tí ń pa ìdájọ́ mọ́? Ẹni tí n ṣe ohun tí ó tọ́. Rántí mi, OLúWA, Nígbà tí o bá fi ojúrere rẹ hàn, wá sí ìhà mi nígbà tí ìwọ bá gbà wọ́n, Kí èmi kí ó lè jẹ ìgbádùn àlàáfíà àwọn tí ìwọ ti yàn, kí èmi kí ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn, ìní rẹ láti jọ yìn ọ́ lógo. Àwa ti dẹ́ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti ṣe, àwa ti ṣe ohun tí kò dá a, a sì ti hùwà búburú Nígbà tí àwọn baba wa wà ní Ejibiti, iṣẹ́ ìyanu rẹ kò yé wọn, wọn kò rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú rẹ, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí ọ níbi Òkun, àní níbi Òkun pupa Ṣùgbọ́n o gbà wọ́n là nítorí orúkọ rẹ láti jẹ́ kí agbára ńlá rẹ di mí mọ̀ O bá Òkun pupa wí, ó sì gbẹ; o sì mú wọn la ìbú já bí aginjù O gbà wọ́n là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn láti ọwọ́ ọ̀tá ni o ti gbà wọ́n Omi ya lu àwọn ọ̀tá wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí èyí tí ó yè nínú wọn. Nígbà náà wọn gba ìpinnu rẹ gbọ́ wọ́n sì kọrin ìyìn rẹ.