ORIN DAFIDI 106:1-12

ORIN DAFIDI 106:1-12 YCE

Ẹ yin OLUWA! Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ta ló lè sọ iṣẹ́ agbára OLUWA tán? Ta ló sì lè fi gbogbo ìyìn rẹ̀ hàn? Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń ṣe ẹ̀tọ́, àwọn tí ń ṣe ohun tí ó tọ̀nà nígbà gbogbo. Ranti mi, OLUWA, nígbà tí o bá ń ṣí ojurere wo àwọn eniyan rẹ. Ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí o bá ń gbà wọ́n là. Kí n lè rí ire àwọn àyànfẹ́ rẹ kí n lè ní ìpín ninu ayọ̀ àwọn eniyan rẹ, kí n sì lè máa ṣògo pẹlu àwọn tí ó jẹ́ eniyan ìní rẹ. A ti ṣẹ̀, àtàwa, àtàwọn baba wa, a ti ṣe àìdára, a sì ti hùwà burúkú. Nígbà tí àwọn baba ńlá wa wà ní Ijipti, wọn kò náání iṣẹ́ ìyanu rẹ, wọn kò sì ranti bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ti pọ̀ tó. Ṣugbọn wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá Ògo lẹ́bàá òkun pupa. Sibẹsibẹ, ó gbà wọ́n là, nítorí orúkọ rẹ̀; kí ó lè fi títóbi agbára rẹ̀ hàn. Ó bá òkun pupa wí, òkun pupa gbẹ, ó sì mú wọn la ibú já bí ẹni rìn ninu aṣálẹ̀. Ó gbà wọ́n là lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra wọn, ó sì kó wọn yọ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. Omi bo àwọn ọ̀tá wọn, ẹyọ ẹnìkan kò sì là. Nígbà náà ni wọ́n tó gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, wọ́n sì kọrin yìn ín.