O. Daf 106:1-12

O. Daf 106:1-12 YBCV

Ẹ fi iyìn fun Oluwa! Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa: nitoriti o ṣeun: nitoriti ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Tali o le sọ̀rọ iṣẹ agbara Oluwa? tali o le fi gbogbo iyìn rẹ̀ hàn? Ibukún ni fun awọn ti npa idajọ mọ́, ati ẹniti nṣe ododo ni igbagbogbo. Oluwa, fi oju-rere ti iwọ ni si awọn enia rẹ ṣe iranti mi: fi igbala rẹ bẹ̀ mi wò. Ki emi ki o le ri ire awọn ayanfẹ rẹ, ki emi ki o le yọ̀ ninu ayọ̀ orilẹ-ède rẹ, ki emi ki o le ma ṣogo pẹlu awọn enia ilẹ-ini rẹ. Awa ti ṣẹ̀ pẹlu awọn baba wa, awa ti dẹṣẹ, awa ti ṣe buburu. Iṣẹ iyanu rẹ kò yé awọn baba wa ni Egipti; nwọn kò ranti ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ; ṣugbọn nwọn ṣọ̀tẹ si ọ nibi okun, ani nibi Okun pupa. Ṣugbọn o gbà wọn là nitori orukọ rẹ̀, ki o le mu agbara rẹ̀ nla di mimọ̀. O ba Okun pupa wi pẹlu, o si gbẹ: bẹ̃li o sìn wọn là ibu ja bi aginju. O si gbà wọn là li ọwọ ẹniti o korira wọn, o si rà wọn pada li ọwọ ọta nì. Omi si bò awọn ọta wọn: ẹnikan wọn kò si kù. Nigbana ni nwọn gbà ọ̀rọ rẹ̀ gbọ́: nwọn si kọrin iyìn rẹ̀.