Iṣẹ́ rẹ ti pọ̀ tó, OLúWA! Nínú ọgbọ́n ni ìwọ ṣe gbogbo wọn: ayé kún fún àwọn ìṣẹ̀dá á rẹ. Bẹ́ẹ̀ ni Òkun yìí tí ó tóbi, tí ó sì ni ìbú, tí ó kún fún àwọn ẹ̀dá alààyè ní ìsàlẹ̀ láìníye ohun alààyè tí tóbi àti kékeré. Níbẹ̀ ni ọkọ̀ ń lọ síwá sẹ́yìn, àti Lefitani, tí ìwọ dá láti ṣe àríyá nínú rẹ̀. Àwọn wọ̀nyí ń wò ọ́ láti fún wọn ní oúnjẹ wọn lákòókò rẹ̀. Nígbà tí ìwọ bá fi fún wọn, wọn yóò kó jọ; nígbà tí ìwọ bá la ọwọ́ rẹ̀, a tẹ́ wọn lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere. Nígbà tí ìwọ bá pa ojú rẹ mọ́ ara kò rọ̀ wọ́n nígbà tí ìwọ bá mú ẹ̀mí wọn lọ, wọn ó kú, wọn ó sì padà sí erùpẹ̀. Nígbà tí ìwọ rán ẹ̀mí rẹ, ni a dá wọn, ìwọ sì tún ojú ayé ṣe. Jẹ́ kí ògo OLúWA wà pẹ́ títí láé; kí inú OLúWA kí ó dùn ní ti iṣẹ́ rẹ̀ Ẹni tí ó wo ayé, tí ó sì wárìrì, ẹni tí ó fọwọ́ tọ́ àwọn òkè, tí wọ́n yọ èéfín. Ní gbogbo ayé mi ní n ó kọrin sí OLúWA: èmi ó kọrin ìyìn sí OLúWA níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè. Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ mi kí ó tẹ́ ọ lọ́rùn bí mo ti ń yọ̀ nínú OLúWA. Ṣùgbọ́n kí ẹlẹ́ṣẹ̀ kúrò láyé kí ènìyàn búburú má sì sí mọ́.
Kà Saamu 104
Feti si Saamu 104
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Saamu 104:24-35
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò