ORIN DAFIDI 104:24-35

ORIN DAFIDI 104:24-35 YCE

OLUWA, ìyanu ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ! Ọgbọ́n ni o fi dá gbogbo wọn. Ayé kún fún àwọn ẹ̀dá rẹ. Ẹ wo òkun bí ó ti tóbi tí ó sì fẹ̀, ó kún fún ọ̀kẹ́ àìmọye ẹ̀dá, nǹkan abẹ̀mí kéékèèké ati ńláńlá. Ibẹ̀ ni ọkọ̀ ojú omi ń gbà lọ, ati Lefiatani tí o dá láti máa ṣeré ninu òkun. Ojú rẹ ni gbogbo wọn ń wò, fún ìpèsè oúnjẹ ní àkókò. Nígbà tí o bá fún wọn, wọn á kó o jọ, nígbà tí o bá la ọwọ́, wọn á jẹ ohun dáradára ní àjẹyó. Bí o bá fojú pamọ́, ẹ̀rù á bà wọ́n, bí o bá gba ẹ̀mí wọn, wọn á kú, wọn á sì pada di erùpẹ̀. Nígbà tí o rán ẹ̀mí rẹ jáde, wọ́n di ẹ̀dá alààyè, o sì sọ orí ilẹ̀ di ọ̀tun. Kí ògo OLUWA máa wà títí lae, kí OLUWA máa yọ̀ ninu iṣẹ́ rẹ̀. Ẹni tí ó wo ilẹ̀, tí ilẹ̀ mì tìtì, tí ó fọwọ́ kan òkè, tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yọ èéfín. N óo kọrin ìyìn sí OLUWA níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè. N óo máa kọrin ìyìn sí Ọlọrun mi, níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀mí mi bá ń bẹ. Kí àṣàrò ọkàn mi kí ó dùn mọ́ ọn ninu nítorí mo láyọ̀ ninu OLUWA. Kí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ parẹ́ lórí ilẹ̀ ayé, kí àwọn eniyan burúkú má sí mọ́.