O. Daf 104:24-35

O. Daf 104:24-35 YBCV

Oluwa, iṣẹ rẹ ti pọ̀ to! ninu ọgbọ́n ni iwọ ṣe gbogbo wọn: aiye kún fun ẹ̀da rẹ. Bẹ̃li okun yi ti o tobi, ti o si ni ibò, nibẹ ni ohun ainiye nrakò, ati ẹran kekere ati nla. Nibẹ li ọkọ̀ nrìn: nibẹ ni lefiatani nì wà, ti iwọ da lati ma ṣe ariya ninu rẹ̀. Gbogbo wọnyi li o duro tì ọ; ki iwọ ki o le ma fun wọn li onjẹ wọn li akokò wọn. Eyi ti iwọ fi fun wọn ni nwọn nkó: iwọ ṣí ọwọ rẹ, a si fi ohun rere tẹ́ wọn lọrùn. Iwọ pa oju rẹ mọ́, ara kò rọ̀ wọn: iwọ gbà ẹmi wọn, nwọn kú, nwọn si pada si erupẹ wọn. Iwọ rán ẹmi rẹ jade, a si da wọn: iwọ si sọ oju ilẹ di ọtun. Ogo Oluwa yio wà lailai: Oluwa yio yọ̀ ni iṣẹ ọwọ rẹ̀. O bojuwo aiye, o si warìrì: o fi ọwọ kàn òke, nwọn si ru ẹ̃fin. Emi o ma kọrin si Oluwa nigbati mo wà lãye: emi o ma kọrin iyìn si Ọlọrun mi ni igba aiye mi. Jẹ ki iṣaro mi ki o mu inu rẹ̀ dùn: emi o mã yọ̀ ninu Oluwa. Jẹ ki awọn ẹlẹṣẹ ki o run kuro li aiye, ki awọn enia buburu ki o má si mọ. Fi ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.